Tánkà agbépo tó sọ ìjánu rẹ̀ nù kọlu kẹ̀kẹ́ Maruwa lọja Oje n'Ibadan, èèyàn mẹ́ta kú, àwọn mìíràn kán léegun ẹ̀yìn

Oríṣun àwòrán, Other
Ẹkun sọ niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹta yii, nigba ti ọkọ agbepo tanka ti ile ise epo rọbi Bovas kan sọ ijanu rẹ nu ti o si kọlu kẹkẹ Napep kan nibi ti eeyan mẹta ti ku.
Bakan naa ni a gbọ wi pe awọn eeyan mii farapa yana yana ninu ijamba ọkọ ọhun.
O-soju-mi-koro kan ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe ọkọ naa ti sọ ijanu rẹ nu lati agbegbe Bẹẹrẹ ki o to lọ kọlu keke Maruwa to n gbe ero ni agbegbe Ọja Oje, ati awọn to n ta ọja lẹgbẹẹ opopona ohun.
Awọn to wa ni agbegbe naa nigba ti iṣẹlẹ naa waye so fun wa pe ọpọ eeyan lọ ba iṣẹlẹ naa lọ ti awọn miran si farapa yana yana.
A tun gbọ wi pe awọn ọlọja ti wọn n ta eso ọsan ati awọn eso miran lọ fara kaasa julọ ninu iṣẹlẹ naa.
Eeyan mẹta lọ k lẹsẹ kẹsẹ, eegun ẹyin eeyan mẹta kan
"Lati agbegbe Bode ni ọkọ agbepo naa ti n jaa bo, nigba ti o de agbegbe Bẹẹrẹ, nise ni wọn pariwo wi pe ki awon eeyan kuro lọna.
Ẹni ti o wa ọkọ ajagbe elepo naa bu sẹkun nibi iṣẹlẹ ọhun.
Onikẹkẹ maruwa ja ero rẹ kan silẹ tan ko jade kuro pada ni ọkọ ajagbe elepo naa kọlu u nibẹ.
Eeyan mẹta lo ku, ẹnìkan da leegun ẹyin, awọn meji kan lẹsẹ, ẹsẹ mejeji lokan,'' Tunrayo Arike ti ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ loju rẹ lo sọ bẹẹ.
Arike tun ṣalaye siwaju si pe awọn oṣiṣẹ adoola emi tete de lati wa doola ẹmi awọn to farakasa ninu iṣẹlẹ naa.
Olaosun Samuel oṣiṣẹ ajọ ẹgbẹ alagbelebu Pupa, Red Cross ṣalaye wi pe ẹgbẹ naa lo kọkọ de agbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ti awọn si doola ẹmi awọn mẹta kan to farapa.
''Bawọn eeyan ṣe n ta ọja loju titi lewu''
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ panapana Ipinlẹ Oyo, Ogbeni Amao ṣalaye wi pe awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa to marun-un.
Ọgbẹni Amao ni "ṣadeede ni wọn pé ile ise wa pe ọkọ to gbẹ epo bentiroolu ti kolu awọn eeyan ni agbegbe Ọja Oje.
Kiakia ni a gbera lati wa sibẹ, ohun ti a ri ni wi pe ọpọ eeyan ni wọn padanu ẹmi wọn, ti awọn miran si farapa.
Yoo to eeyan marun ti mo ri to fara kaasa ninu iṣẹlẹ naa, imoran mi fun awọn eeyan ni wi pe bii wọn ti n ta ọja lẹgbẹ opopona lewu, papa julo awọn to n ta ọja laarin opopona ati ẹgbẹ opopona.
Bi a ti a de ibi iṣẹlẹ ijamba naa ti waye ni a da omi si ara ọkọ agbepo naa ki ọkọ naa ma ba gbana".


























