Ìdí rèé tí àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, TUC, NULGE àti JNC fi fagilé ìfẹ̀họ́núhàn tí wọ́n fẹ́ ṣe tako bánkì UBA l'Osun

Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, TUC, NULGE ati JNC ẹka ti ipinlẹ ọsun ti fagile ifẹhonuhan wọn fẹ ṣe tako ile ifowopamọ UBA ni ipinlẹ Osun.
Lọsẹ to kọja ni awọn agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Osun ti kede pe ifẹhonuhan naa yoo waye ni ọjọ kẹrinlelogun osu yii lori bi ile ifowopamọ UBA ṣe kọ lati gbẹsẹ kuro lori owo ijọba ibilẹ to wa ni akata wọn.
Ti ẹ ko ba gbagbe pe, awuyewuye naa ko sẹyin bi Gomina Ademola Adeleke ṣe fi ọwọ osi juwe ile fun awọn alaga ijọba ibilẹ ti Gomina tẹlẹ ri, Gboyega Oyetola yan ko to kuro nipo.
Bakan naa, ile ẹjọ kotẹmilọrun to kalẹ si ilu Akure nipinlẹ Ondo gbe idajọ kalẹ pe, ki awọn alaga naa ko pada si ọfiisi ni ọjọ Kẹwaa osu Keji ọdun 2025.
Eleyii si mu ki awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ yanṣẹ lodi fun osu mọkanla gbako ti wọn ko ṣi lọ si ọfiisi wọn.
Awọn alaga ijọba ibilẹ ti ile ẹjọ kotẹmilọrun da pada naa ni wọn ti gba ọfiisi ijọba ibilẹ lati osu kẹwaa ọdun 2025 di asiko yii.
Amọ, awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Osun ati awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ fariga pe, awọn ko le bawọn alaga naa ṣiṣẹ papọ lati igba naa.
Ki lo kan ile ifowopamọ UBA lori ọrọ awọn alaga ijọba ibilẹ Osun?
Ohun to kan ile ifowopamọ UBA lori ọrọ yii ni pe wọn fẹsun kawọn alaga ijọba ibilẹ ti gomina Adeleke fi ọwọ osi juwe ile fun pe wọn lẹdi apo papọ pẹlu ile ifowopamọ UBA ti banki apapọ Naijiria san owo awọn ijọba ibilẹ Osun ṣi.
Eleyii lo mu ki gomina Adeleke ati awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ ọsun kigbe sita ti wọn si gbe ile ifowopamọ UBA lọ si ile ẹjọ lasiko naa lati mọ ṣe san owo ijọba ibilẹ kankan fun awọn alaga ijọba ibilẹ naa.
Ṣugbọn ni ọjọ Kẹtalelogun osu Kẹta ọdun ti awa yii, ni ijokoo waye laarin awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, TUC, NULGE ati JNC pẹlu awọn ajọ DSS ati ile ifowopamọ UBA.
Ohun ti ipade naa da le lori ni pe, ki wọn fagile ifẹhonuhan to fẹ waye ni ọjọ Kẹrinlelogun osu Kẹta yii, ki awọn ki awọn le jọ sọ asọyepọ lori owo naa.
Ṣaaju lawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ti fun ile UBA ni gbedeke ọsẹ kan eyi to ti bẹrẹ lati ọjọ Kẹtalelogun osu Kẹta si ọgbọn ọjọ osu Kẹta yii lori ọrọ naa.
Ki ni alaga NLC ẹka ti ipinlẹ Osun sọ?
Christopher Arapasopo, ẹni to jẹ alaga fun ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ẹka ti ipinlẹ Osun ti salaye idi ti awọn fi fagile ifẹhonuhan ti wọn fẹ ṣe tẹlẹ .
Kọmureedi Arapasopo ni igbesẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ lati fagile ifẹhonuhan ọhun ko sẹyin bi ajọ eleto aabo DSS ṣe sọ pe ki awọn si lọ ni suruu diẹ naa lori ọrọ to wa nilẹ.
Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ni awọn ti fun ile ifowopamọ UBA ni ọsẹ kan pere lati ṣe ohun to tọ ati lati ma ṣe ṣan owo kankan fun awọn alaga ijọba ibilẹ ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn jẹ gaba si ọfiisi bayi.
Kọmureedi Arapasopo tun fi kun pe bi ile ifowopamọ UBA ba kọ lati ṣe ojuṣe eyi to tọ, awọn yoo jade fun ifẹhonuhan ti agbara ijọba apapọ gan an ko ni ka ọrọ naa mọ.
O ni akoko awọn alaga ijọba ibilẹ to jẹ gaba si ọfiisi ti pari lati osu kẹwaa ọdun 2025 to kọja.
Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ tun sọ pe awọn alaga naa ko ni ẹtọ kankan lati ṣe ni ọfiisi mọ rara.
Wamu wamu ni awọn ẹsọ alaabo duro si gbogbo ẹka ile ifowopamọ UBA to wa ni ilu Osogbo lonii ọjọ Iṣẹgun nitori ifẹhobuhan to fẹ waye tẹlẹ.



























