À n ṣiṣẹ́ kárakára láti dáàbò bò àwọn èèyàn Kwara- Kọmiṣọnna ọlọ́pàá Kwara

Oríṣun àwòrán, Woro Community
Oga ọlọpaa ipinlẹ Kwara, CP Ojo Adekimi ti fi awọn eeyan Kwara lọkan balẹ pe agbofinro n ṣiṣẹ karakara lati fopin si iṣoro eto aabo to n koju ipinlẹ naa lasiko yii.
Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara sọ eyi lẹyin iṣẹlẹ ibugbamu ado oloro to waye nibẹ lọjọ kẹtalelogun, oṣu keta, ọdun 2026 ni agbegbe Woro ni Kaiamo.
Ileeṣẹ olọpaa sọ pe wọn ri ado oloro naa sinu ilẹ ni lopopona Woro to so ipinlẹ Kwara papọ mo ipinlẹ Niger ni.
Wọn ni pe ọkọ akero kan lo n lọ lati Kaiamọ lọ si Borgu nipinlẹ Niger nibi ti Zubairu Inuwa to jẹ awakọ naa si ti gbẹmi mi bayii.
Nafisat Mohammed ati ikoko ọmọ rẹ ni wọn ti n gba itọju nile iwosan.
Kọmiṣọnna sọ ninu atejade to fi sita pe wọn tun ti fi ọpọ ọmọ ogun ranṣẹ si agbegba naa fun aabo to peye.
Àdó olóró bú gbàmù nílùú Woro ní Kwara, ẹ̀mí ṣòfò, ọ̀pọ̀ èèyàn farapa
Awọn ara ilu Woro ni ijọba ibilẹ Kaiama ni Ipinlẹ Kwara tun ti wa ninu iporuuru ọkan bayii latari ibugbamu to sẹlẹ ni ilu naa ni owurọ oni ọjọ kẹtalelogun osu kẹta ọdun yii.
Ohun ti a gbọ ni pe ọkọ ero kan lo fara kaa sa ado oloro naa, eyi to ṣeku pa dẹrẹba ọkọ naa, nibi ẹlomiran si fara pa yanna yanna nibi iṣẹlẹ ọhun.
Ohun to sokunfa iṣẹlẹ yii si ṣokunkun si awọn eniyan titi di akoko yii.
Iwadii fi han pe akọkọ kọ leyii ti ibugbamu yoo sẹlẹ ni ilu naa, akọkọ iru rẹ ni eyi to waye ni ọjọ kẹta osu keji ọdun yii.
Igba naa ni awọn agbebọn seku pa ọgọọrọ eniyan, wọn si tun ko ọpọlọpọ awọn obinrin ati ọmọ wẹwẹ lọ.
Lati igba naa, awọn eniyan ti wọn ji ko tii gba ominira titi di asiko yii ti Ibugbamu tun sẹlẹ.
Aráàlú Woro sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
BBC News Yoruba ba araalu Woro sọrọ lati mọ kulẹkulẹ ohun ti o sẹlẹ gan an.
Olori ọdọ ilu naa, Baloude Najeem ti BBC Yoruba ba sọrọ lori ago sọ pe nnkan bi aago mẹjọ aarọ ni iṣẹlẹ naa waye.
"Ọkọ ero kan lo n bọ wa sinu ilu wa lati ọna Kaiama, ni nnkan bi aago mẹjọ aarọ oni.
"Orukọ dẹrẹba ọkọ naa ni Shuaib, o si jẹ ọmọ ilu Wọrọmọkoto, ilu naa ko ju ilu mẹta lọ si ilu Woro.
"Igba ti wọn fẹ wọ inu igboro ilu Woro ni Ibugbamu yii sẹlẹ, o si gbẹmi dẹrẹba naa.
"Ibugbamu yii waye gẹlẹ ni ibi ti takọkọ ti waye nigba ti awọn agbebọn wa lati yinbọn pa awọn araalu.''
Olori awọn ọdọ fikun ọrọ rẹ pe "ijamba naa pin awakọ ọkọ naa yẹlẹyẹlẹ, koda, ko si eeyan kan to le da a mọ.
"Awọn mẹta ni wọn wa ninu ọkọ naa, dẹrẹba ọkọ, iya kan pẹlu ọmọ rẹ ti ko tii ja lẹnu ọmu.
"Iya yii o ku sugbọn, yatọ si pe o farapa, oju rẹ kan fọ, ẹsẹ rẹ kan si ge pẹlu.
"Wọn ti gbe iya yii digba-digba lọ si ile iwosan ni Ilorin ti i ṣe olu ilu Ipinlẹ Kwara.''
Nǹkankan ò ṣe ọmọ ọmú kan tó wà nínú ọkọ naa.
Olori ọdọ naa salaye pe ibi ti wọn ti ri ẹnjini ọkọ naa to opo ina kan si ibi ti iṣẹlẹ naa ti sẹlẹ, ti ara yooku si fọn ka.
Ọgbẹni Najeem salaye pe o see ṣe ki iṣẹlẹ naa jẹ isẹ ọwọ awọn agbebọn ti wọn wa sọsẹ ninu osu keji ọdun yii.
"Wọn le jẹ awọn agbebọn ti wọn wa sọsẹ saaju, nitori o jọ isẹ ọwọ wọn.
"A o mọ ohun ti wọn tun fẹ ṣe bayii o, o le jẹ awọn soja ti wọn n daabo bo ilu ni wọn fẹ pa.
"O si tun le jẹ pe wọn kan fẹ ran ijọba leti pe awọn si wa ni agbegbe naa ni wi pe awọn si tun le sọsẹ ni igbakugba.''



























