Àwọn ẹlẹ́rìí EFCC sọ fún ilé ẹjọ́ bí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ṣe wọ akoto owó tó nííṣe pẹ̀lú Malami

Oríṣun àwòrán, ABUBAKAR MALAMI/FACEBOOK
Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti ṣàgbékalẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí méjì láti tako Mínísítà fún ètò ìdájọ́ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Abubakar Malami, ìyàwó rẹ̀, Bashir Asabe àti ọmọ rẹ̀ Abdualaziz ní ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja.
Malami, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ ló ń kojú ìgbẹ̀jọ́ ẹlẹ́sùn mẹ́rìndínlógún tó níṣe pẹ̀lú ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ èyí tí EFCC fi kàn wọ́n.
Àmọ́ wọn ti jiyàn gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n kà síwọn lọ́rùn.
Níbi ìgbẹ̀jọ́ náà tó wáyé lọ́jọ́ Ajé ni EFCC ti pe àwọn ẹlẹ́rìí náà níbi tí agbẹjọ́rò EFCC, Jibrin Okutepa ti ṣáájú ẹlẹ́rìí Simon Daniel Kwayil, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ Union Bank.
Ẹlẹ́rìí náà sọ fún ilé ẹjọ́ pé ní oṣù Kejìlá, ọdún 2025 ni EFC kọ lẹ́tà ránṣẹ́ sílé ìfowópamọ́ àwọn láti bèèrè fún àtẹ̀ bí owọ ṣe ń ọlé tó sì ń jáde ní akoto owó nọ́mbà 0179011105, tó jẹ́ ti iléeṣẹ́ Meethaq Hotels Limited.
Ilé ẹjọ́ gba ìwé náà wọlé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí.
Kwayil sọ fún ilé ẹjọ́ pé ìyàwó Malami nìkan ló ní àṣẹ láti gba owó jáde kúrò nínú akoto owó náà.
Ó sọ fún ilé ẹjọ́ pé owó tó tó mílíọ̀nù májìdínláàádọ́ta náírà ni wọn fi ránṣẹ́ láti akoto owó Meethaq Hotels Limited sáwọn akoto owó tó jẹ́ ti Abubakar Malami àti A.A. Malami & Co. láàárín ọjọ́ Kejì, oṣù Kejì sí ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹrin ọdún 2024.
Ẹlẹ́rìí náà sọ fún ilé ẹjọ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù ló wọlé, tó sì jáde ní akoto owó Meethaq Hotels Limited láàárín ìgbà náà.
Ó fi kun pé láàárín ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kejìlá ọdún 2022 sí ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹrin ọdún 2023, owó tó lé ní N99m ló wọ akoto owó náà.
Nígbà tí agbẹnusọ olùjẹ́jọ́ ń fi ọ̀rọ̀ wá ẹlẹ́rìí náà lẹ́nu wà, ó sọ pé owó kankan kò wọ akoto owó náà láti àjọ tàbí iléeṣẹ́ ìjọba kankan.
Kwayil ní òun kò mọ ohun tí àwọn owó náà wà fún.
Ohun tí ẹlẹ́rìí kejì sọ
Olùpejọ́ náà tún pe ẹlẹ́rìí míì, Olomotane Egoro tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ Access Bank.
Egoro sọ fún ilé ẹjọ́ pé EFCC bèèrè àwọn ìwé kan lọ́wọ́ òun tó fi mọ́ àwọn ohun tí wọ́n lò láti fi ṣí akoto owó àti bí owó ṣe ń wọlé àti jáde sí akoto owó Agro Allied Limited and Khadimiya for Justice and Development Initiative ní ilé ìfowópamọ́ náà lọ́dún 2025.
Ilé ẹjọ́ gba ìwé náà wọlé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí.
Ẹlẹ́rìí náà sọ fún ilé ẹjọ́ pé Abdulaziz, tó jẹ́ ọmọ Malami ló ni akoto owó Agro Allied Limited.
Ó sọ pé iléeṣẹ́ náà gba ẹ̀yáwó N400m lọ́wọ́ ilé ìfowópamọ́ náà èyí tí wọ́n fún-un lọ́jọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹwàá, ọdún 2020 èyí tí wọ́n da padà pé ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje, ọdún 2022.
Nígbà tí agbẹjọ́rò Malami ń fi ọ̀rọ̀ wá ẹlẹ́rìí náà lẹ́nu wò, ó sọ pé òun kò mọ ohun tí owo náà wà fún tàbí ohun tí wọ́n fi ṣe.
Bákan náà ló sọ fún ilé ẹjọ́ kò sí owó kankan tó wọ akoto náà láti iléeṣẹ́ tàbí àjọ ìjọba.
Lẹ́yìn èyí ni adajọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà, Joyce Abdumalik sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin, ọdún 2026.


























