Kí ló dé tí ẹnu ń kun Peller, bí obìnrin kan ṣe gbé e lọ sílé ẹjọ́, tí ààfin Ọba Benin sì tún korò ojú sí àbẹ̀wò rẹ̀?

Habeeb Hamzat Adelaja wọ aṣọ funfun, ó ń wo ọ̀ọ́kán

Oríṣun àwòrán, Peller089/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba ìlú Benin ní ìpínlẹ̀ Edo ti kéde pé ó ṣeéṣe kí wọ́n lé ọ̀kan lára àwọn olorì ní ààfin Ọba ìlú Benin kúrò ní ààfin náà.

Ìkéde náà ló ń wáyé lórí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kàn pé olórí náà lọ́wọ́ nínú bí gbajúmọ̀ orí ayélujára Habeeb Hamzat Adelaja tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Peller ṣe wọ ààfin náà láì gba àṣẹ tó yẹ.

Ìkéde yìí ló ń wáyé nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ìgbìmọ̀ náà, Frank Irabor fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta.

Peller tó ń ṣe àbẹ̀wó sáwọn ìpínlẹ̀ káàkiri ní Nàìjíríà ṣàbẹ̀wó sí ìlú Benin ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹta níbi tí àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ti gbà á ní àlejò. Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba náà ní àbẹ̀wò Peller lòdì sí òfin tó de ṣíṣe àbẹ̀wò sí ààfin náà.

"Ààyè ohun àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ni ààfin Ọba ìlú Benin, kìí ṣe fún fídíò orí ayélujára"

Àtẹ̀jáde náà ní àwọn ti ránṣẹ́ pe Peller láti yọjú sáwọn olóyè tó wà ní ààfin náà láti wá wí tẹnu rẹ̀.

"Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba ìlú Benin fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Habeeb Hamzat Adelaja, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Peller ríbi wọ ààfin lọ́nà àìtọ́, láì gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn tó yẹ, tí àbẹ̀wò rẹ̀ sì fa ojútì fún ààfin náà.

"Ààfin Ọba ìlú Benin kìí ṣe ibi tí wọ́n ti le máa ya fídíò fún orí ayélujára nítorí ó jẹ́ ààyè tó kún fún àwọn ohun ìṣura ohun àṣà àti ìṣẹ̀ṣe."

Irabor sọ pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tí àbọ̀ ìwádìí àwọn sì ti kọ́kọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àtàwon olóyè kan ló wà nídìí bí Peller ṣe wọ ààfin náà.

Ó sọ pé olóyè kan tí ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ti sọ pé kó lọ rọ́kún nílé fún ìgbà kan ná, tí àwọn ọlọ́pàá sì ti ń fi ọ̀rọ̀ wá òṣìṣẹ́ ààfin míì lẹ́nu wò fẹ́sùn pé ó gba èèyàn láyè láti wọ ààfin láì sí àṣẹ.

Ó fi kun pé olorì kan tí ìwádìí tún fi hàn pé ó lọ́wọ́ nínú bí Peller ṣe wọ ààfin ló ti ń kojú ìgbẹ́jọ́, tó sì ṣeéṣe kí wọ́n yọ ọ́ kúrò láàfin tí adé ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá ṣí mọ lórí.

Ó tẹ̀síwájú pé ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba náà ránṣẹ́ sí Peller láti yọjú sáwọn olóyè kan ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì ń bèèrè pé kó yọjú láìpẹ́ bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwọn máa fi òfin dá sí ọ̀rọ̀ náà.

Obìnrin míì gbé Peller lọ sílé ẹjọ́ fún ìbánilórúkọjẹ́

Nínú ìròyìn míì, arábìnrin kan Osarobo Odigie ti wọ Peller lọ sílé ẹjọ fẹ́sùn pé ó bu òun àti pé ó gbé ohun tó jẹ́ ìkọ̀kọ̀ òun sí gbangba.

Odigie gbé ìgbésẹ̀ ofin tako Peller látàrí ìfaǹfà kan tó wáyé láàárín àwọn méjéèjì ní ilé ìgbafẹ́ kan tó wà ní òpópónà Lekki-Epe Expressway, ìpínlẹ̀ Eko.

Ẹ ó rántí pé ní oṣù Kìíní, ọdún 2026 ni Peller kọ́kọ́ gbé fídíò ohun tó wáyé láàárín òun àti arábìnrin náà léde ṣùgbọ́n tó padà tọrọ àforíjì fún gbígbe fídíò rẹ̀ jáde láì gba àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.

Ṣùgbọ́n Odigie tó ń ra oúnjẹ nílé ìgbafẹ́ náà lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé sọ pé fídíò tí Peller gbé jáde náà mú kí àwọn èèyàn máa bú òun lọ́nà àìtọ́.

Ó wá ń bèèrè fún owó ìtanràn tí iye rẹ̀ jẹ́ N395m gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn látàrí àwọn ìbanilórúkọ jẹ́ tó wáyé sí òun lórí fídíò náà tí Peller gbé sórí afẹ́fẹ́.

Ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni ìgbàgbọ́ wà pé ìgbẹ́jọ́ náà máa bẹ̀rẹ̀ tí àwọn méjéèjì kò bá fẹnukò lórí ọ̀nà tí wọ́n fi máa parí ìfaǹfà náà láì lọ sílé ẹjọ́.