Àwọn jàndùkú ya wọ ọ́fíìsì Amotekun l'Osun, jí ìbọn wọn gbé sálọ

Ọkunrin tawọn janduku lu ni ọfiisi Amọtẹkun l'Osun

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn janduku agbenọ ṣe ikọlu si ọfiisi awọn Amọtẹkun to wa ni Ilu Awo ni ijọba ibilẹ Ẹgbẹdore nipinlẹ Osun.

‎Idije bọọlu la gbọ pe o fa ariyanjiyan laaarin awọn ọkunrin meji niluu Awo lalẹ ọjọ Aiku ọjọ Kejilelogun Osu Kẹta Ọdun yii.

Nigba to di alẹ ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹta ni ọkan lara wọn dena de ẹnikeji pẹlu awọn janduku.

Gẹgẹ bi alukoro ajọ Amọtẹkun Ọṣun, Yusuf Idowu, ṣe ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita, wọn dawọ jọ lu ọkunrin naa pẹlu igi, ada atawọn nnkan ija miran.

Bi o ṣe jaja bọ ni o sare wọ inu ọfiisi awọn Amọtẹkun lọ fun aabo ẹmi rẹ.

‎Ṣugbọn ṣe ni awọn janduku naa pada wa si ọfiisi awọn Amọtẹkun, wọn si ya bo awọn Amọtẹkun ti wọn ba ni ọfiisi naa, wọn si bẹrẹ sii lu wọn lalubami.

A gbọ wi pe wọn ba ọpọlọpọ nnkan jẹ, bẹẹ ni wọn tun gbe ibọn awọn Amọtẹkun salọ.

‎Ọgbẹni Idowu sọ siwaju sii pe lẹyin gbogbo wahala ti wọn fa lọwọ Amọtẹkun pada tẹ marun-un lara awọn janduku ọhun.

Awọn Amotekun si ti fa wọn le awọn ọlọpaa Ilu Awo lọwọ fun ijiya to tọ ati to yẹ labẹ ofin.

‎Alukoro ẹṣọ Amotẹkun ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ṣawari awọn ibọn ti awọn janduku ọhun gbe lọ.

Bakan naa ni o rọ awọn araalu lati fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn agbofinro nipa titawọn lolobo nigba kugba lori iṣẹ iwadii naa.

Ki ni ọlọpaa ipinlẹ Osun lori iṣẹlẹ naa?

Abiodun Ojelabi ẹni to jẹ alukoro fun awọn ọlọpaa ipinlẹ Osun ṣalaye pe iroyin naa ti de eti awọn, awọn si ti bẹrẹ iwadi lori ọrọ naa.

‎Abiodun ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Osun ti da awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ si Ilu Awo ati agbegbe rẹ bayi lati le ri okodoro ọrọ naa.

‎Ṣugbọn titi di asiko ti a n koroyin yii jọ, ọfiisi ajọ Amọtẹkun to wa niluu Awo nipinlẹ Ọṣun ko tii ri ibọn ti awọn janduku ti wọn ya bo wọn ni ọfiisi gba pada.