Àwọn agbésùnmọ̀mí tó jí ọmọ ìjọ ECWA mẹ́jọ gbé ní Kwara ń bèèrè bílíọ̀nù kan náírà fún ìtúsílẹ̀ wọn

Ijọ ECWA tawọn ajinigbe ti gbe ọmọ ijọ mẹjọ lọ niluu Omugo nipinlẹ Kwara.

Oríṣun àwòrán, ECWA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn agbebọnja to ji eeyan mẹjọ gbe nile ijọsin ECWA nilu Omugo ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ Kwara ti beere fun biliọnu kan naira kawọn to le fi wọn silẹ.

Oniwaasu ijọ ECWA ilu Omugo, Ẹniọwọ Sunday Timothy Ọmọle lo sọrọ yii loni Ọjọru ọjọ Karundinlọgbọn oṣu yii.

Lasiko to n ba aṣoju kọroyin ile iṣẹ BBC Yorùbá sọrọ lo fidi rẹ mulẹ pe awọn ajinigbe naa ti pe lalẹ ana ọjọ Iṣẹgun ọjọ kérinlelogun oṣu Kẹta yii.

Eniọwọ Omole salaye pe ẹrọ ibanisọrọ ọkan lara awọn ti wọn ji gbe ni wọn lo lati fi pe ti awọn si gbe lọ fun ẹni to gbọ ede Hausa.

O tẹsiwaju pe awọn ajinigbe naa ni awọn fẹ ba Kabiyesi ilu naa sọrọ tori biliọnu kan naira lawọn o gba kawọn to le fi wọn silẹ.

O salaye pe awọn ajinigbe ọhun awọn n binu gidigidi pe awọn eeyan ilu naa gba ijọba laye lati ko awọn ọmọ ogun wa si ilu naa.

Pẹlu alaye pe, awon Fulani ti wọn o mọwọ mẹsẹ lawọn Ologun pa, wọn o ri awọn agbesunmọmi naa pa.

Ẹniọwọ Ọmọle fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹjọ lo wa lakata awọn ajinigbe naa ninu eyi ti obirin jẹ marun un, ọkunrin mẹta, agbalagba si ni gbogbo wọn.

Alufaa ijọ ECWA tun sọ pe iyawo oun naa wa lara awọn to wa lakata awọn ajinigbe ati baba agbalagba ẹni aadọrun ọdun to jẹ odi.

O tẹsiwaju pe awọn fi milionu kan naira bẹ wọn, wọn yari pe koda awọn o ni gba aadọta milionu naira.

O ni titi di asiko yii awọn o ti ri awọn aṣoju ijọba ibilẹ Ifẹlodun.

O tun dupẹ lọwọ awọn ọdẹ ati awọn ologun ti wọn n ṣọ ilu naa bayii pẹlu alaye pe Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti sabẹwo si ilu naa lọjọ ti iṣẹlẹ yii waye.

O wa parọwa si ijọba ipinlẹ Kwara ati ijọba ibilẹ Ifẹlodun lati ran awọn lọwọ ni ilu naa nitori agbara awọn o ka ohun ti awọn agbebọnja naa beere.

Alufaa Omole ni awọn mọlẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe ti bẹrẹ ipade lori iṣẹlẹ naa.

Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ aiku ọjọ kejilelogun oṣu yii lawọn agbesunmọmi ya wọ ile ijọsin ECWA niluu Omugo ni ẹkun Oroagọ nijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ Kwara ti wọn si ji eeyan mọkanla gbe, ṣugbọn wọn pada yọnda awọn mẹta ninu wọn.

Lati igba naa lawọn eeyan ilu naa o ti loju orun mọ.

Ọpọ awọn eeyan ilu naa lo ti sa kuro nitori ibẹru bojo to gba ọkan wọn.

Awọn olujọsin naa wa ninu isin ọjọ isinmi lasiko tawọn agbebọnja kọlu ile ijọsin naa.

Lara awọn ti wọn ji gbe ni iyawo Oníwàásù ijọ naa ti wọn yọ ọmọ ọdun kan to pọn sẹyin rẹ kuro lasiko ti wọn n lọ lọna.

Ijọba ipinlẹ Kwara ti fi atẹjade kan sita nibi ti kọmisọna feto irọyin ati ibanisọrọ Arabinrin Bọlanle Olukoju ti sọ pe ijọba n ṣiṣẹ pẹlu awọn eleto aabo lati doola awọn ti wọn ji gbe.

Ọkan lara ilakaka awọn ẹṣọ alaabo ni bi wọn ti doola awọn mẹta ninu wọn.

Ilu Omugo ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara n koju iṣoro eto aabo.

Ilu naa to wa lẹkun Oroagọ jẹ ibi ti ipenija eto aabo wa ni ipinlẹ Kwara.

Lana ni awọn agbebọnja sekupa awọn ọlọdẹ meji ti wọn tẹlẹ awọn kan ti wọn fẹ lọ sin oku mama wọn lopopona Oke Ọyan .

Inu ibẹru-bojo lawọn eeyan agbegbe naa wa, isẹ agbẹ si ni iṣẹ wọn ṣugbọn wọn o le lọ oko mọ.