Agbébọn 38 pàdé ikú lọ́wọ́ ológun Naijiria, wọ́n gba ìbọn AK-47 àti àdó olóró lọ́wọ́ wọn

Awọn ọta ibọn ati ado oloro ti wọn gba lọwọ awọn agbebọn naa.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ikọ apapọ ologun ti a mọ si Joint Task Force lapa Ariwa Ila-oorun Naijiria ti kede pe ko din ni agbebọn mejidinlogoji (38) tawọn pa ninu ikọlu to waye ni Madaragrau, nijọba ibilẹ Biu nipinlẹ Borno.

Ikọ ti a tun a mọ si Operation Hadin Kai naa sọ pe owurọ kutu ọjọ Satide, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ni awọn mu awọn eeyan naa balẹ.

Atẹjade ti ileeṣẹ ologun ilẹ wa fi kede aṣeyọri naa, lati ọwọ Ọgagun Sani Uba, to n ri si ikede nileeṣẹ ologun, tẹsiwaju pe ibọn AK -47 meje lawọn gba lọwọ awọn agbebọn lasiko ti iṣẹ ọhun n lọ lọwọ, ati awọn ado oloro pẹlu .

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Diẹ lara awọn oku naa

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Ninu alaye ikọ ologun apapọ yii ni wọn ti sọ pe:

"Ikọ yii kọlu awọn ISWAP ti ibẹru-bojo ti mu ni kutu hai ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026, ni FOB Mandaragirau, ẹka keji.

"A koju awọn alatako naa pẹlu dídọdẹ wọn tẹlẹ, a si mu ki wọn da tọwọ wọn silẹ."

Wọn fi kun un pe lẹyin eyi ni awọn ologun tun ṣina si oju ọna tawọn ẹlẹgiri naa n gba, o si to mejindinlogoji ti wahala ba ninu wọn bi wọn ṣe sọ.

Wọn fi kun un pe awọn ri oku mẹjọ ninu wọn loju ọna nitosi ibi tawọn yi wọn po si naa.

Oku eeyan mi-in to tun ju ọgbọn lọ ni awọn araalu paapaa sọ pe awọn tun ri pẹlu nnkan ija lara wọn loju ọna Garin Mallum–Garin Gajere, titi de Timbuktu Triangle, bi ileeṣẹ ologun naa ṣe wi.

"Eyi foju han pẹlu ẹjẹ to ṣan kalẹ ati awọn nnkan ija ti wọn da silẹ.

"A tun ri ibọn AK-47 meje gba pẹlu ọta ibọn mẹjọ, ado oloro RPG mẹrin atawọn nnkan ija ọlọkan-o -jọkan."

Ọgagun Uba sọ pe iku awọn agbebọn yii dun mọ awọn eeyan agbegbe naa pupọ, ti wọn si n ṣọpẹ pe ikọ ologun wa nitosi awọn.

O fi kun un pe iṣẹ n tẹsiwaju lagbegbe Garin Mallum – Garin Gajere titi de Timbuktu Triangle, lati ṣawari oku awọn ẹlẹgiri to le ṣẹku sawọn oju ọna yii.

Ẹ o ranti pe lọsẹ to kọja yii ni ikọ ologun Operation Hadin Kai yii kede pe oun mu agbebọn to le lọgọrin (80), balẹ nipinlẹ Borno kan naa, pẹlu alaye pe ẹrujẹjẹ olori ikọ naa mẹta wa lara awọn to deru ọrun.