Àwọn àgbẹ̀ oníkòkó méjì tó ṣẹ́kù sí àkàtà àwọn ajínigbé nínú mẹ́rin tí wọ́n jí gbé níléeṣẹ́ kòkó n'Ibadan ti gba ìtúsílẹ̀

Aworan ẹnu ọna abawọle CRIN niluu Ibadan

Oríṣun àwòrán, CRIN

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ẹsọ alaabo ti gba itusilẹ awọn agbẹ onikoko meji ti awọn ajinigbe ji gbe lasiko ti wọn ṣe abẹwo si ileeṣẹ to n ṣe iwadii nipa Cocoa ni Naijiria (CRIN) niluu Ibadan lọjọ Ṣatide.

Awọn ọlọpaa ti kọkọ gba meji silẹ lara awọn agbẹ naa, ti ọwọ si tẹ afurasi mẹta to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa laarin wakati mẹrinlelogun ti iṣẹlẹ naa waye .

Bakan naa ni a ri gbọ pe awon ajinigbe naa bẹrẹ fun Ọgbọrun milọnu naira ṣaaju ki wọn to fi awọn eeyan naa silẹ.

Alaga ijọba ibilẹ Oluyole, Onimọ ẹrọ Akeem Olatunji, lo fidi rẹ mulẹ awọn eeyan naa ti gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe.

Olatunji ṣalaye pe itusilẹ awọn agbẹ naa waye nitori iṣẹ takuntakun awọn agbofinro pẹlu ikọ Amọtẹkun ati awọn fijilante ni ijọba ibilẹ Oluyole.

Agbébọn ya bo iléeṣẹ́ ìjọba fún ìwádìí Kòkó n‘Ibadan, wọ́n jí àgbẹ̀ mẹ́rin gbé, ẹnìkan móríbọ́
Awọn agbebọn pẹlu ibọn lọwọ wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn agbebọn ya bo ọọfisi ajọ to n ṣewadii nipa cocoa, Cocoa Research Institute of Nigeria (CRIN) to wa ni Idi-Ayunre, niluu Ibadan, nibi ti wọn ti ji agbẹ mẹrin gbe lọ.

A gbọ pe abẹwo ni awọn kan lara awọn ti wọn ji gbe naa lọ ṣe sibẹ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.

Agbẹ cocoa kan ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa sọ pe inu igbo lawọn agbesunmọmi naa gba wa, ti wọn si di ọkọ wọn lọna lasiko ti wọn n lọ si ẹka eto ilera ọgba ajọ naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka to fidi iroyin naa mulẹ sọ fun awọn akọroyin pe wọn doola ẹnikan ninu awọn agbẹ mẹrin naa.

O ni kọmiṣona ọlọpaa, Femi Haruna, ti paṣẹ fun ẹka to n gbogun ti ijinigbe, Anti-Kidnapping Unit ati DPO Idi-Ayunre ki wọn bẹrẹ iṣẹ lati gba awọn eeyan to ṣi wa lahamọ ajinigbe naa pada.

PPRO Ayanlade fi kun pe awọn agbofinro ti kan lu igbo lati wa awọn eeyan naa ri ki ọwọ si tẹ awọn kọlorọsi to ṣiṣẹ ọhun.

O fi kun pe ẹni ti wọn doola wa ni alaafia bayii, o si ti n fun awọn ọlọpaa ni awọn iroyin to le wulo fun iwadii.

Ayanlade sọ pe "Iṣẹ n lọ lọwọ lati doola awọn eeyan to ṣi ku si ahamọ awọn ajinigbe naa."

Alaye ohun ti ọlọpaa sọ

Ninu atẹjade ti Ayanlade fi lede, o ni "Nigba ti a gbọ pe wọn ji awọn eeyan naa gbe, akojọpọ awọn ọlọpaa, ajọ NSCDC, Amotekun atawọn fijilante ni wọn lọ sibẹ lati le awọn ajinigbe naa ba.

"Akitiyan wa ṣe aṣeyọri, a si doola ọkunrin meji.

"Lasiko ti iṣẹ naa n lọ lọwọ, a fi ṣikun ofin mu afurasi mẹta, wọn si ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii.

"A fẹ fi da gbogbo araalu loju pe a ko ni yẹsẹ ninu ojuṣe wa lati tẹsiwaju lati maa daabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan kaakiri ipinlẹ yii.

"A fẹ ki awọn araalu lọ fi ọkan wọn balẹ, ki wọn si maa ṣọra, ki wọn tun fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro nipa fifun wọn ni iroyin to le ran wa lọwọ ninu iwadii to n lọ lọwọ."