Wọ́n fí mí ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí ọmọ mi kú torí mo ṣe àtìlẹyìn fún Tinubu – Remi Surutu

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Bi a ṣe n gbaradi fun eto idibo gbogbo ni ọdun 2027 lorilẹede Naijiria, ọpọ oṣere tiata ati eekan ilu lo tun ti ko arawọn jọ lati kede atilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu pe ko lọ fun saa keji gẹgẹ bii Aarẹ orilẹede Naijiria.
Ọpọ awọn oṣere yii wa nibi ifilọlẹ EKO57, ẹgbẹ kan ti wọn sẹda lati ṣe atilẹyin saa keji Aarẹ Bola Tinubu.
Ninu fọnran to lu sita lori ayelujara, ọpọ awọn oṣere bi Adams Kehinde ti ọpọ mọ si Lege Maimi, Yomi Fash, Remi Surutu, Aremu Afolayan ati bẹbẹ lọ lo peju si ifilọlẹ naa, ti wọn si kede atilẹyin fun Aarẹ.
Orin a n bẹ lẹyin rẹ ni awọn eeyan yii mu bọ ẹnu, ti wọn si na oṣuṣu ọwọ, tii se ami idamọ ẹgbẹ oṣelu APC soke.
Bakan naa ni awọn osere tiata to peju sibi iwọde ita gbangba naa lati se atilẹyin fun saa keji Tinubu tun wọ asọ ati ẹgbẹjọda, ti wọn ya ami fila Tinubu si pẹlu awọ ẹgbẹ oselu APC.
Mo fi mi ṣe yẹyẹ nigba ti ọmọ mi ku nitori mo ṣe atilẹyin fun Tinubu - Remi Surutu
Gbajugbaja oṣere tiata, Remilekun Oshodi, ti ọpọ mọ si Remi Surutu ti sọrọ sita lori ohun to lakọja lasiko eto idibo ọdun 2023 nitori o ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu.
Oshodi sọ eyi lasiko ifilọlẹ EKO57, ẹgbẹ kan to n pe fun atilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu fun saa keji gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Naijiria.
Oshodi ni ọpọ awọn eeyan lori ayelujara lo bẹrẹ si ni ina abuku si lasiko ti o padanu ọmọ rẹ obinrin pe eyi waye nitori o n ṣe oṣelu.
"Eru ko ba mi, mo ti n ṣe ipolongo ibo fun ọpọ ọdun. Awọn eeyan ti bu mi lori ayelujara, wọn sọ ọpọ nnkan.
"Koda wọn ni Asiwaju ti mo n tẹle lo pa mi ni ọmọ ṣugbọn ọrọ radarada ni.
"Nigba ti mo pada Baba Tinubu, o n ṣe daada, ti o ba rope Tinubu ko ṣe daada, fa eeyan kanlẹ ni idile rẹ, ẹ jẹ ki eeyan wa tukọ ijọba fun ọjọ kan."
Wo awọn oṣere ti wọn ni awọn kabamọ pe awọn ṣe atilẹyin fun Aarẹ Tinubu
Ọrọ yii lo ti fa ọpọ ariyanjiyan lori ayelujara, bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn oṣere tiata ni anfani lati atilẹyin fun ẹnikẹni to ba wu wọn, ni awọn kan n bu ẹnu atẹlu lu wọn pe ko ye ki wọn ṣe bẹẹ pẹlu bi araalu ṣe n la ọpọ inira kọja lasiko yii.
Bẹẹ ba gbagbe, ọpọ awọn oṣere lo jade sita lẹyin eto idibo ọdun 2023 to gbe Aarẹ Tinubu wọle pe wọn ka bamọ pe wọn ṣe atilẹyin fun ijọba to wa lode lasiko
Lara wọn ni Ronke Oshodi Oke, ẹni to bu sẹkun, to si ni oun kabamọ pe oun ṣiṣẹ fun wọn to n ṣe ijọba lasiko idibo.
Bakan naa ni agbaọje oṣere Yoruba, Ganiu Nafiu, ti ọpọ mọ si Alapini ti sọ pe oun kabamọ pe oun polongo ibo fun Aarẹ Bola Tinubu lọdun 2023.
Alapini sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe lori tẹlifisan African A-List TV nibi to ti sọ nipa bo ti bẹrẹ iṣẹ ere ori itage ati awọn ipenija ilera to ti koju.
Ọgbẹni Nafiu sọ pe nnkan to buru jai ni bi Tinubu ati ọmọkunrin rẹ, Seyi Tinubu, ko ṣe ranti awọn oṣere to le ni ọgọrun mọ lati ṣe nnkan fun wọn tori atilẹyin ti wọn se fun.
Ko tan sibẹ, Gbajugbaja oṣere tiata mii, Ebun Oloyede ti ọpọ mọ si Olaiya Igwe ti tọrọ aforijin lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria fun bi o se lọ si eti okun lati lọ gbadura fun aṣeyọri Aarẹ Bola Tinubu ninu eto idibo Aarẹ ọdun 2023.



























