Ìjà tí a kò mọwọ́ mẹsẹ̀ là ń jẹ́ lórí èlé owó epo, orí àgbà ẹ̀tù ní Nàíjíríà jókòó lé - NLC

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC pẹlu asia ẹgbẹ naa ti wọn gbe dani

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria (Nigeria Labour Congress) ti ni ki ijọba apapọ Naijiria dide iranwọ fun araalu, latari owo epo to ti gbowo lori latigba ti ogun ti bẹrẹ ni Middle East.

Ana ọjọ Aiku ni NLC pe ipe yii ninu atẹjade ti wọn pe akọle rẹ ni "Save Nigerians From This Shock: An Urgent Relief Has Become Necessary."

Aarẹ NLC, Joe Ajaero lo buwọ lu atẹjade naa.

Atẹjade naa ṣalaye pe o yẹ kijọba Naijiria dide kia lati ṣeto owo iranwọ fun awọn oṣiṣẹ, ṣe adinku owo ori, pese owo igbaye-gbadun ki wọn si tun awọn ibudo ifọpo Naijria ṣe.

NLC sọ pe epo bẹtiroolu ti wọn ti n ta ni N1,170 si N1,300 bayii ti mu aye le fun ọpọ oṣiṣẹ Naijiria atawọn araalu pata.

Wọn kilọ pe ohun to le fa aibalẹ ọkan ati rogbodiyan leyi, bijọba ko ba tete dide si i.

"Ìyà tawon ọmọ Naijiria ko mọ nipa rẹ ni wọn n jẹ"

Ni itẹsiwaju alaye awọn NLC, wọn ni ijọba Naijiria fi awọn eeyan ilu rẹ silẹ lati maa jiya ogun ti wọn ko mọwọ mẹsẹ nibẹ.

Ogun to n waye ni Middle East naa ni NLC sọ pe o fi han bi ailera ṣe n ba ẹka epo Naijiria finra to, ti araalu si n tori rẹ jiya ti ko kan wọn.

"NLC n ke gbajare lorukọ ẹgbẹlẹgbẹ oṣiṣẹ ọmọ Naijiria ti ohun ẹkun wọn ko de etigbọ ijọba, ti wọn si n jiya lọwọ awọn alagbara agbaye.

" Ifiyajẹni taara leyi jẹ fun awọn ọmọ Naijiria. Bi awọn alagbara ṣe n fi bọọmu jagba loke okun, ogidi iya lo n koju awọn oṣiṣẹ Naijiria nibi. Ebi n pa wọn, oṣi n ta wọn nitori a ti kuna lati jẹ kawọn ibudo ifọpo tiwa ṣiṣẹ."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

"Ojuṣe ijọba ni lati ro osisẹ lagbara kia, ki i ṣe ki wọn maa purọ mọ ogun to n lọ lọwọ laarin US ati Iran"

NLC fi kun un pe niwọn igba ti Naijiria ba ṣi n ba owo epo to n lọ soke lagbaye finra, ti wọn ko tun ibudo ifọpo tilẹ yii ṣe, bi yoo ti maa ri ti araalu yoo maa jiya naa ree ni gbogbo igba ti rogbodiyan ba n ṣẹlẹ lagbaaye.

Wọn ni owo ọkọ to wọn n fa inira fun oṣiṣẹ lati de ibi iṣẹ wọn, afikun ba iye awọn nnkan eelo ati jijẹ lọja. NLC sọ pe ori agba ẹ̀tú ibọn ni Naijiria jokoo le pẹlu ohun to n ṣẹlẹ yii.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ni opo to gbe orilẹede ro, wọn ko gbọdọ wo latari ijiya.

Wọn ni ojuṣe ijọba ni lati ro wọn lagbara kia, ki i ṣe ki wọn maa purọ mọ ogun to n lọ lọwọ.

Ẹ o ranti pe ogun Iran ti Israel ati America n ṣagbatẹru rẹ yii lo fa a ti ileeṣẹ epo Dangote naa fi ṣafikun iye jala epo, to si n tẹle ohun ti ogun naa ba gbe wa lati fi diye le owo epo.

Bakan naa ni awon ileepo kaakiri Naijiria naa ti fi kun owo epo pẹlu latari ogun yii, eyi to ti mu owo ọkọ, ounjẹ atawọn nnkan mi-in gbowo leri si i.