Agbábọ́ọ̀lù Super Eagles nígbà kan rí, Henry Nwosu dágbére fáyé

henry Nwosu ko ti dagbere faye

Oríṣun àwòrán, Segun Odegbami

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agbabọọlu Super Eagles nigba kan ri, Henry Nwosu ti jade laye.

Akẹgbẹ rẹ, Segun Odegbami, lo fi ikede iku agba ọjẹ agbabọọlu ọhun lede lọjọ Abamẹta.

Odegbami sọ pe iku oloogbe naa waye lẹyin to ba aisan kan finra fun odidi ọjọ marun un gbako.

Ninu ikede naa, Odegbami sọ pe "lẹyin to ti ba aisan finra fun odidi ọjọ marun nile iwosan, ẹni ti mo maa n pe ni 'Youngest Millionaire' ti fi aye silẹ ni aago mẹrin aarọ oni nile iwosan fasiti ipinlẹ Eko nibi to ti wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun lati Ọjọru."

Odegbami ni pẹlu ọgbẹ ọkan loun fi kede iku oloogbe ọhun.

Lẹyin naa lo gbadura pe ki Eledua tẹ si afẹfẹ rere.

Henry Nwosu wa lara awọn to kopa ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika, Afcon, fun Naijiria lọdun 1980.

Lasiko idije naa lọdun 1980, Nwosun lo kere julọ ninu gbogbo awọn agbabọọlu to ṣoju Naijiria.

Iku Nwosu yii lo n waye lẹyin ọjọ diẹ ti olukọni Super Eagles tẹlẹ, Adegboye Onigbinde naa jade laye.

Onigbinde lo ko awọn agbabọọlu Super Eagle lọ si idije ife ẹyẹ agbaye FIFA World Cup to waye ni Japan ati South Korea lọdun 2002.

Nwosu ati Onigbinde ko ipa ribiribi ninu bọọlu afẹsẹgba Naijiria gẹgẹ bii agbabọọlu Green Eagles lẹyin ọdun 1980.

Ẹni ọdun mejilelọgọta ni Henry Nwosu ko to dagbare faye.