NBA,Ẹgbẹ́ Amòfin Naijiria bínú sí Sowore tó pàtẹ ìpàdé akọ̀ròyìn nínú kóòtù

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore/ X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Akojọpọ ẹgbẹ awọn amofin lorilẹede Naijiria; Nigerian Bar Association (NBA) ti sọ pe iwa to lodi sofin gbaa ni ajafẹtọọ ọmọniyan ati oloṣelu, Omoyele Sowore, hu nigba to patẹ ipade awọn akọroyin sinu yara igbẹjọ.

Ilu Abuja ni iṣẹlẹ naa ti waye lanaa ọjọ Iṣẹgun, nile ẹjọ giga kan.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ NBA, Afam Osigwe, fi sita l'Ọjọru lo ti ni iwa yowu to ba tako iyi ile ẹjọ, ṣẹruba awọn amofin tabi di igbẹjọ lọwọ, lodi si ofin ẹgbẹ amofin orilẹede Naijiria.

Atẹjade naa fi kun un pe ko si aaye fun ẹnikẹni lati tabuku kootu, ati pe ohun ti Sowore ṣe ko ṣee gba bẹẹ rara.

Wọn ni iwa to hu tumọ si dida omi alaafia kootu ru ni.

Ki ni Sowore ṣe ni kootu?

Gẹgẹ bi atẹjade awọn NBA naa ṣe ṣalaye, wọn ni Sowore wọ yara igbẹjọ ile ẹjọ giga ilu Abuja naa pẹlu awọn eeyan kan to tẹle e lẹyin ti wọn n fi foonu wọn ya a.

Wọn fi kun un pe wọn tun gbe awọn irinṣẹ ayaworan miran dani pẹlu.

"Wọn kora jọ lati bẹrẹ ohun to jọ ipade oniroyin ninu yara igbẹjọ.

"Awọn ọmọ ẹyin rẹ naa ṣeto ohun to jọ itage ti eeyan ti fẹẹ sọrọ, lẹyin naa si ni oun funra rẹ wọ yara to wa ninu lọ to si jokoo sori tabili kan, to si bẹrẹ si I sọrọ lori awọn ohun to n ṣẹlẹ niluu."

Atẹjade naa fi kun un pe ẹjọ Sowore ko si ninu eyi ti wọn fẹ pe, bẹẹ ni agbẹjọro kankan ko ba a wa.

Eyi ni wọn lo di wahala ninu yara igbẹjọ, to si di ohun ti Adajọ agba kan, Musibau Adetunji (SAN) ko o loju lati ma ṣe huwa to lodi si ofin yara igbẹjọ.

"Iwa yowu to ba tẹ ofin ile ẹjọ mọlẹ tabi da igbẹjọ ru, lodi si ofin ẹgbẹ amofin Naijiria (NBA)"

Bẹẹ ni atẹjade naa wi.

Wọn fi kun un pe loootọ ni araalu lẹtọọ lati wa si kootu ki wọn si ri ohun ti wo ohun ti wọn n ṣe nibẹ, amọ ko tumọ si pe ki eeyan waa sọ yara igbẹjọ di ibudo ipade awon oniroyin.

Alaye Sowore

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu fidio to ṣafihan iṣẹlẹ naa ni Omoyele Sowore ti n sọ fun Amofin to n ba a sọrọ, pe ko sohun to lodi sofin lati sọrọ nipa idajọ ninu kootu.

Amofin agba naa n ṣalaye pe o ti fẹrẹ pe ọgbọn ọdun ti oun ti n ṣiṣẹ lọya bọ, oun ko ri ẹnikẹni ko maa ṣepade oniroyin ninu kootu ri.

Lọọya sọ pe amofin agba ni oun, SAN, Sowore naa si fesi pe agbẹnusọ agba fun awọn araalu ni oun naa ( Senior Advocate of the Masses).

Amofin kọju si awon akoroyin, o ni yoo daa ki won gbe e ipade wọn naa lọ sita, ṣugbọn Omoyele Sowore tun sọ pe lọya naa ko le sọ pe koun ma ba wọn sọrọ nigba toun ṣi n duro de Adajọ lọwọ, nigba to jẹ ọrọ to kan alaafia loun n sọ.

O ni ti DSS ba de, to ti geeti kootu pa, awọn amofin ko ni i sọrọ, oun ni wọn n pa ohun mọ agogo rẹ lẹnu.

Sowore sọ pe lọya naa n huwa ikonilayajẹ foun ni.

O fi kun un pe oun ko si ninu yara lọya, fun idi eyi, ko laṣẹ lati le oun jade.

Bẹẹ ni wọn n gba ọrọ naa mọra wọn lọwọ, ko too di ọjọ keji ti NBA fi atẹjade to koro oju si iwa Sowore sita.

Amọ NBA duro lori ofin to de iwa naa, wọn si ni ki gbogbo ile ẹjọ tubọ ri I daju pe awọn eeyan n tẹle ofin bo ṣe yẹ.

Èrò aráàlú

Yatọ si awọn NBA to koro oju si iwa Sowore, ọpọ araalu ati awọn eeyan to mọ nipa ofin kootu ni wọn n sọ pe iwa to lodi si ofin kootu ni Sowore hu.

Ọpọ eeyan to n da si ọrọ naa lori ayelujara lo n fidi ẹ mulẹ, pe kootu ki I ṣe ibi ti eeyan yoo ti maa huwa bo ṣe wu u, nitori ofin to de ihuwasi pọ ni kootu gan-an.

Lara ofin bẹẹ ni eyi to ṣẹlẹ si Sowore yii, ti i ṣe pe eeyan ko gbọdọ ya aworan ninu kootu, ka ma ti I sọ pe ki tọhun patẹ ipade kankan.

Ọmọwe Ahmed Isau (ACTI), ọkan lara awọn to ṣalaye iwa ti Sowore hu, sọ pe iwa to lodi sofin lo hu.

Ninu atẹjade ti Ọmọwe Isau kọ lo ti ni bi kootu tilẹ jẹ aaye ti araalu le wọ, ki I se ibi ti eeyan ti n patẹ ipade rara.

O ni bi aaye ba wa fun eeyan lati sọrọ, ki I ṣe bii ko sọ yara kootu di ibi ipade oniroyin, koda bi igbẹjọ ko ba si.

Ọmọwe Isau sọ pe awọn iwa to maa n din iyi ofin ku ni iru eyi ti Sowore hu yii, nibi ti wọn ba ti n fọwọ pa ida ofin lo si ti maa n waye bo ṣe sọ.