Afẹ́fẹ́ òjò fa ìjàmbá ọkọ̀ ńlá l'Osogbo

Lẹyin ti ọpọ eeyan ti n rawọ ẹbẹ fun ojo latari ooru lile to n mu kaakiri orilẹede Naijiria lasiko yii, ojo kan ro lalẹ ana ti i ṣe ojọ kejinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2026 niluu Osogbo, ipinlẹ Osun.
Ṣugbọn afẹfẹ to fẹ bi ojo ọhun ṣe n rọ lagbegbe Aregbe, lo fa ijamba to run ọkọ tirela kan jegejege, to jẹ wọn fa awakọ yọ labẹ rẹ ni.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Ni deede aago mẹjọ alẹ ọjọ Àbámẹ́ta naa ni ojo to mu afẹfẹ nla dani naa rọ to si ba ọpọlọpọ nnkan jẹ niluu Osogbo.
Lasiko ti afẹfẹ ọhun n fẹ lọwọ ni ọkọ ileeṣẹ ọti ẹlẹrindodo kan to gbajumọ n bọ lati ilu Ibadan.
Bo ṣe de agbegbe Arẹgbẹ niluu Osogbo ni afẹfẹ ojo naa gbe irin nla kan ti wọn fi ṣe patako ipolowo ọja sẹba ọna, ti wọn ti ri mọlẹ lati ọjọ to ti pẹ.
Bi afẹfẹ naa ṣe gbe e lo wolu ọkọ ọti ẹlẹrindodo naa mọlẹ.
Gẹgẹ bi ẹnikan to wa ni agbegbe naa lasiko iṣẹlẹ yii ṣe ṣalaye fun BBC, iyẹn Babatunde Kazeem, o ni afẹfẹ ojo naa pọ to bẹẹ to fi jẹ pe ọpọlọpọ ina igbalode (Solar) ti ijọba ṣe si opopona naa ni afẹfẹ ojo yii wo to si bajẹ.
Àdá, àáké àti ọwọ́ ni wọn fi yọ awakọ nibi to ha si
Nipa bi awakọ tirela naa ko ṣe ku ninu iṣẹlẹ yii, Kazeem ṣalaye pe gbogbo eeyan lo ti sọ ireti nu lori rẹ, wọn ro pe o ti ku sinu ọkọ naa ni ṣugbọn ori ko o yọ.
Pẹlu igbiyanju ọpọlọpọ eeyan ni wọn fi doola ẹmi awakọ naa bo ṣe wi, ti wọn yọ ọ kuro nibi to ha si.
Ẹnikan to kọ lati darukọ ara rẹ fun wa ṣalaye pe ko si awọn eleto ilera to le doola ẹmi awakọ naa nitosi lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.
O fi kun un ko tun si ohun tawọn eeyan le tete lo lati yọ awakọ naa jade.
Awọn nnkan bii ada, aake ati ọwọ awọn eeyan lo ni wọn n lo lati le ri I pe wọn doola ẹmi awakọ naa ti ori ko yọ.
O wa rọ ijọba lati mojuto aabo awọn eeyan ti wọn ṣe ijọba le lori.
Ẹwẹ, Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun ti ba awọn to fara gba ninu ijamba afẹfẹ ojo naa kẹdun.
Ninu atẹjade kan ti Olawale Rasheed, Akọwe iroyin fun Gomina fi sita ni wọn ranṣẹ ibanikẹdun naa si.
























