Wo bí òfin tuntun nípa gbígba físà ilẹ̀ Gẹẹṣi ṣe kan akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Naijiria tó ń lọ kàwé ní UK

wọn alejo ni UK

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fun ọpọ awọn ọdọ ni Naijiria, lilọ silẹ okeere lati kẹkọọ jẹ ọkan lara ala ọjọ iwaju wọn.

Awọn kan maa n sọ pe awọn nifẹ ati lọ kẹkọọ nilẹ okeere nitori bi eto ẹkọ wọn ṣe daa to, paapaa bi wọn ko ṣe ki n da iṣẹ silẹ, fun awọn mii, o jẹ lati japa fun wọn.

Lara awọn orilẹede ti awọn ọmọ Naijiria fẹran ati maa japa lọ ni ilẹ Gẹẹsi.

Lọdun 2025, o le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn ọmọ Naijiria to lọ silẹ Gẹẹsi, eyii to n tumọ si pe ọpọ ọmọ Naijiria lo fẹran orilẹede ọhun.

Amọ ṣa, lati ọdun 2025 kan naa ni ijọba UK ti gbe awọn ofin tuntun sita, to si n ṣe atunṣe si awọn ofin to wa nilẹ tẹlẹ, eyii to n mu ko nira fun ọpọ awọn to fẹ japa UK.

Iwọyin ni awọn ofin tuntun marun un ti UK gbe sita to n mu ki ọna ati lọ kawe ati japa ṣoro fun awọn ọmọ Naijiria.

Fisa gbigba lori ayelujara

Lati ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2026 ni ijọba UK sọ pe oun yoo maa fun awọn eeyan ni fisa lori ayelujara dipo eyii ti wọn maa n lẹ mọ iwe irinna wọn tẹlẹ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, oju opo UKVI ẹni to ba fẹ lọ UK ni yoo ti ri fisa naa, yoo si jẹ ki fisa gbigba maa ya kankan.

Amọ ṣa, awọn eeyan yoo nilo ontẹ Electronic Travel Authorisation (ETA) fun awọn ti yoo ṣabẹwo ranpẹ.

Ede Gẹẹsi ṣe pataki ju tẹlẹ lọ

Fun awọn to ba fẹ lọ kawe tabi ṣiṣẹ, wọn gbọdọ ṣe idanwo ti yoo fidi rẹ mulẹ pe wọn gbọ, wọn le kọ, wọn si le sọ ede Gẹẹsi daadaa, eyii ti wọn n pe ni B2 level, ṣaaju asiko yii, B1 level ni wọn n bere fun ninu ede Gẹẹsi.

Iye owo ti arinrinajo gbọdọ ni lọwọ

Ẹni ti yoo ba lọ si UK bayii gbọdọ pese ẹru maa jẹ mi rinṣo pe oun ni owo to pọ daadaa ninu apo iṣuna oun lati na lọhun.

Eyii mu ko nira fun awọn ọmọ Naijiria latari pe iye ti wọn n ṣe owo ilẹ Gẹẹsi naa pọ jọjọ si owo Naiijiria.

Iye akoko ti eeyan le ṣiṣẹ to ba kawe tan

Bo tilẹ jẹ pe pupọ awọn to n kawe nibẹ lọwọ le ṣiṣẹ ọdun meji lẹyin ẹkọ wọn, lati ọdun 2027, wọn ko ni le lo ju ọdun kan abọ mọ lẹyin ẹkọ wọn.