Ẹ dákun ẹ gbà mí o, owó dísù ti fẹ́ gbẹ̀mí mi - Èèkàn òṣèré, Kunle Afolayan figbe ta

Oríṣun àwòrán, Kunle Afolayan/ Facebook
Latigba ti afikun ti ba owo epo latari ogun to n lọ lọwọ ni awọn agbegbe Middle East ni araalu ti n kerora, ti kaluku n sọ inira ti wọn n koju latari owo epo to n lọ soke naa.
Ọkan lara awọn eeyan to ti sọrọ soke lori inira naa ni gbajumọ oṣere tiata, Kunle Afolayan, ẹni to ni agbara oun ko gbe ẹgbẹrun kan aabọ naira ti wọn n ta jala epo disu bayii.
Kunle Afolayan to ṣalaye ara rẹ loju opo Instagram lọjọ Iṣẹgun, sọ pe awin ni oun n gba epo naa latigba to ti gbowo lori.
Oṣere tiata to tun jẹ adari awọn okoowo ati ibudo ti wọn ti n ya sinima ti wọn si tun n ṣe faaji, ṣalaye pe oun n na to miliọnu mọkanla (₦11 million ) lori disu rira laarin ọsẹ mẹrin si marun-un.
"Inu mi ko dun latigba ti wahala yii ti bẹrẹ, nitori mi o lagbara ₦1,500 fun lita disu kan"
Gẹgẹ bi Kunle to jẹ ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe Adeyemi Afolayan (Adelove) ṣe wi:
"Ninu ọkan lara awọn ileeṣẹ ti mo n dari, KAP Village, a maa n na miliọnu mọkanla naira lorii disu laaarin ọsẹ mẹrin si marun-un. A si ni ina Solar, ṣugbọn a ṣi n na to miliọnu mọkanla naira."
"Awin la n ra disu ti a n lo. Nigba ti a ba pawo diẹ, a maa wa ọna lati san gbese. Nigba mi-in, o maa n to oṣu meji ka too le sanwo silẹ ka si gba omiran lawin."
"Nisinyi to ti di ₦1,000, tabi ₦995 si ₦1,500, ko ṣee ra rara. Bi ẹ ba le ran wa lọwọ, ma a dupẹ pupọ."
Bẹẹ ni Kunle Afolayan ṣalaye ninu fidio to fi soju opo Instagram naa.
Oṣere naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun n lo ina Solar, lilo epo disu yii ni opo to gbe iṣẹ oun ro, to si le jẹ koun maa ri ina ọba lo lai ṣẹju.
Nigba ti owo disu si ti gunke réré bayii, Afolayan tawọn eeyan tun mọ si Aresẹjobata ni agbara oun o gbe e.
Tẹ o ba gbagbe, ogun Iran to bẹrẹ, eyi ti America ati Israel n lewaju rẹ lo ṣokunfa ọwọngogo epo rọbi gbogbo.
Ileeṣẹ Dangote to maa n din owo epo ku tẹlẹ paapaa si bẹrẹ si i kede afikun owo epo rẹ, to fi dohun ti araalu n ke irora nitori owo epo.

























