Ìdí rèé tí Femi Fani-Kayode àti Dele Momodu fi ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ara wọn

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu/FB/ Femi Fani-Kayode/ Instagram
Lati bii ọjọ meloo kan sẹyin ni gbajumọ akọroyin to tun jẹ oloṣelu; Dele Momodu ati Femi Fani-Kayode;minisita irinajo ofufuru tẹlẹ, ti n sọ kobakungbe ọrọ sira wọn lori ayelujara.
Awọn ọrọ naa le debi pe bi wọn ṣe n fi eebu ara bu ara wọn ni wọn tun n mẹnuba awọn to bi wọn.
Ija oṣelu ni awọn eeyan kọkọ mọ to da Dele Momodu ati Femi Fani-Kayode tawon eeyan mọ si FFK pọ, ko too tun di pe wọn n fi eebu ara ati irandiran bu ara wọn.
Ki lo fa gbas-gbos gan-an?
Yatọ si pe boya Dele Momodu, ọmọ ẹgbẹ ADC ati FFK to n ṣe APC ti le maa ba ara wọn ja labẹnu tẹlẹ, ohun to tun ru wahala jade laarin wọn bayii ni ọrọ ti a gbọ pe Dele sọ nipa Aarẹ Tinubu lori eto tẹlifiṣan kan to ṣe.
Lori eto naa ni iroyin ti ro o pe Momodu fi ijọba Aarẹ Tinubu we ti Apaṣẹ-waa, Oloogbe Ọgagun Sani Abacha.
Ọrọ naa ni Fani Kayode fesi si loju opo ayelujara rẹ, to ni opurọ to n turọ ta bii elubọ ni akọroyin Dele Momodu.
"Aṣiri irọ ti Dele n pa ati ailojuti rẹ ti han sita, bo ṣe fi Tinubu we Abacha ko tọna rara. To ba jẹ Apaṣẹ-waa ni Tinubu, Dele atawọn to n ṣoju fun yoo ti ku tabi ki wọn wa lẹwọn bayii."
Bẹẹ ni FFK wi to si tun kilọ fun Dele Momodu ko yee ba Tinubu jẹ lẹyin to ba a jẹ.
O ni akọroyin ti ileeṣẹ iroyin rẹ ti dohun igbagbe ni, oun funra rẹ ko si jọ ẹni to ba igba mu mọ.
Femi Fani-Kayode sọ pe oun ko jẹ nnkan kan lara Tinubu lati bii ogoji ọdun, ko too di pe oun di ọmọ ẹgbẹ APC ni 2021 toun si polongo ibo fun ni 2023.
O ni latigba naa ni oun ti jẹ olootọ si Tinubu, o ni amọ Dele Momodu ya onijẹkujẹ to n tẹle Atiku, ti iyẹn ko si ni oore kan ti yoo ṣe fun un.
FFK kadi ọrọ rẹ pe ọmọ ile ọla loun, onibiniran si ni oun pẹlu, Dele nikan ni ẹnikan ko mọ, ju pe arebipa ni oun ati idile rẹ lọ.
O ni ki ọkunrin naa lọ mojuto ilera rẹ, nitori irisi rẹ n fẹ akiyesi ati amojuto.
Dele Momodu fesi
Ninu esi Dele Momodu si FFK loju opo X tirẹ naa l'Ọjọbọ, o ni ki awon to n bẹ oun lati ma ṣe fun FFK lesi ma binu, ṣugbọn oun gbọdọ fun un lesi ọrọ rẹ nitori ẹnikan to fẹran lati maa finran ni.
" Mo mọ Femi daadaa, ẹni to fẹran lati maa finran ni, ṣugbọn emi naa raye fun un daadaa.
"O pe iwe iroyin to lorukọ kaakiri agbaye ( Ovation) ni ohun ti ko si mọ, ọjọ kọkanla oṣu Keji ọdun 2026 lo ṣi bẹ mi pe ki n ba oun gbe iroyin jade lori ọkan lara awọn oju opo wa, nipa aṣeyọri rẹ lẹka iwe kika ati idile, mo si ba a gbe e."
Momodu sọ pe FFK fi atẹranṣẹ idupẹ ṣọwọ soun lori rẹ, o ni ṣe o ti wa n ṣe arán bayii ni ko fi ranti mọ, to n pe oun ni akọroyin ana.
O tun sọ bo ṣe lo iwe iroyin to pe loku naa fun ayẹyẹ ọjọọbi ọmọ rẹ ọkunrin, ti oun ko si gba kọbọ lọwọ rẹ koun too ba a lo o.
Momodu tẹsiwaju pe FFK tun fi atẹjiṣẹ idupẹ ranṣẹ lori rẹ.
O sọ bo ṣe ba a da si ija oun ati iyawo rẹ to kọ ọ, nigba ti obinrin naa fẹ koun bẹ FFK ko le jẹ ko maa ri awon ọmọ to da wọn pọ.
" Iṣẹ wo ni Femi n ṣe ju ko maa ṣalẹ jẹ kiri fun ipo oṣelu lọ?
Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Dele Momodu sọ nipa FFK pe:
" Iṣẹ wo ni Femi n ṣe ju ko maa ṣalẹ jẹ kiri fun ipo oṣelu lọ? Gbogbo bo ṣe n janu pe ọmọ olowo loun, orukọ rẹ ko ti i wọnu iwe agbaye fun nnkan gidi ri, afi fun awọn ohun ti ko daa."
Bẹẹ ni Dele Momodu wi nipa Femi Fani-Kayode, pẹlu alaye pe ọrọ rẹ ye oun, o n wa oju rere Tinubu ko le ri ipo aṣoju Germany ti wọn fun un gba ni, to ba si bọ́, ko le baa ri omiran gba ni.
Bẹẹ ni oko ọrọ n sọlẹ lọtun-un losi, laaarin Dele Momodu ati Femi Fani-Kayode, ti ẹnikẹni ko si ti i mọ ibi ti yoo pari si.

























