Igboho gbaná jẹ lórí òkò ọ̀rọ̀ tí Sowore sọ sí i torí àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún Tinubu

Sunday Igboho wọ aṣọ buba, Omoyele Sowore wọ ẹwu alawọ buluu

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore/X/Sunday Igboho/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajijgbara fun idasilẹ Yoruba Nation n ni, Oloye Sunday Adeyemo tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, ti da a pada fun ajafẹtọọ ọmọniyan, Omoyele Sowore lori ọrọ to sọ pe oṣelu jẹ ki n jẹ ni Owo baba Dami n ṣe.

Ọrọ yii jade lẹyin ti Sowore fẹsun kawọn ajijagbara kan wi pe nitori nnkan ti wọn yoo jẹ lo jẹ ki wọn maa ṣatilẹyin fawọn oloṣelu kan.

Sowore sọ ninu fidio naa pe gbogbo nnkan ti Igboho n ṣe lagbo oṣelu bayii to fi mọ atilẹyin rẹ fun Aarẹ Bola Tinubu ko ṣẹyin ọna atijẹ eyi to pe ni ''amala politics.''

Owo Baba Dami sọ ninu atẹjade kan ti adari eto iroyin rẹ, Olayemi Koiki, fi sita pe ọrọ ti Sowore sọ ko lẹsẹ nlẹ, ati pe kii ṣe nnkan to yẹ kawọn eeyan ka kun.

Ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation ṣalaye pe ẹtọ oun ni lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ nilẹ Yoruba ati lati ṣatilẹyin fun Tinubu ko le wọle saa keji gẹgẹ bii aarẹ Naijiria lọdun 2027.

''Mo tako ọrọ ti Sowore sọ wi pe oṣelu jẹ ki n jẹ ni mo n ṣe pẹlu ijijagbara mi nilẹ Yoruba.

Iru ọrọ bayii tabuku igbiyanju wa lati ri pe eto aabo fẹsẹ mulẹ daadaa lawọn ipinlẹ Yoruba ati kaakiri orilẹede Naijiria lapapọ

Igba meloo ni Sowore ṣagbatẹru ifẹhonuhan fun itusilẹ mi?

Igbe aye ti Sowore n gbe gan an tako bo ṣe n sọ pe oun n ja fawọn mẹkunu, tori ile itura ti wọn n gba N450,000 lọjọ kan lo n sun si niluu Eko.

Ko si ẹni to le fipa mu mi lati ṣatilẹyin fawọn oloṣelu bii Atiku Abubakar, Peter Obi, n ko si le ba Sowore gan an ṣiṣẹ pọ,'' Igboho lo sọ bẹẹ.

Eto aabo to fẹsẹ mulẹ ni mo n ja fun nilẹ Yoruba - Igboho

Igboho ṣalaye ninu atẹjade to fi sita naa wi pe eto aabo to fẹsẹ mulẹ kaakiri ilẹ Yoruba lo jẹ oun logun.

O ni nnkan yii gan an ni oun n ja fun, kii ṣe erongba lati dupo oṣelu rara.

Igboho beere lọwọ Sowore nipa bi eto aabo ṣe ri nipinlẹ Ondo to jẹ ipinlẹ rẹ nibi ti iṣẹlẹ ijinigbe, ipaniyan ati oriṣiiriṣii ikọlu ti n waye lera lera.

O ni ikọlu awọn agbebọn lawọn igberiko ati sawọn obinrin to fi mọ awọn ọba alaye loun fẹ ko di ohun igbagbe.

Ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation sọ pe nnkan toun ti n ja fun niyi lati ọdun 2020.

Owo Baba Dami ni bi Sowore ṣe pe akitiyan oun lori eto aabo ni ''amala politics'' tako erongba oun lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ.