Bàbá mi Alafin Oyo fẹ́ràn ipa tí mo kó nínú Sinimá Anikulapo, wọ́n sì fẹ́ wò ó àmọ́... - Adedoja Alaafin

Àkọlé fídíò, Adedoja Adeyemi Alaafin Oyo: Ó wù mí kí n ṣì kópa nínú sinimá tó bá ní ṣe pẹ̀lú àṣà

Ọ kan lara awọn ọmọbinrin Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi Kẹta, Adedoja Adeyemi gbalejo BBC Yoruba to si sọ bi ibaṣepọ laarin oun ati baba rẹ ṣe dan to.

A dedoja ṣipaya eyi lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba to ti n ṣalaye iru baba ti Alaafin jẹ si gbogbo ọmọ rẹ.

Adedoja sọrọ nipa awọn nnkan to maa n wu u lati gbe ṣe ati bo ṣe ri anfani lati ṣe aṣeyọri ninu wọn.

Adedoja Adeyemi

A dedoja ni ko si ohunkohun ti ọmọ Alaafin kankan fẹ ṣe, baba yoo gba awọn nimọran lati kawe na tori Alaafin fẹran iwe gan.

B o ṣe n kawe ti ipele ikẹkọgboye akọkọ ati ikeji naa lo n ṣe awọn nnkan mii pọ bii yiyan bii ologun ati pe o ti nifẹ si ere sinima gan.

B i Adedoja ṣe rin pade gbajugbaja oṣere ati oludari ere, Kunle Anikulapo to si kopa ninu fiimu naa jẹ pataki sii.

Adedoja Adeyemi

" Igba ti mo sọ fun iya mi ati baba mi nipa ere Anikulapo, inu wọn dun sii gan pe ere nipa aṣa ni.

K oda, baba ti ni awọn maa wa wo bi a ṣe n ṣe ere naa lọ tabi ti a ba ti gbe e jade, amọ bo ṣe wu Ọlọrun lo n ṣe ọla rẹ."

A dedoja n sọ eyi nipa bi baba rẹ, Alaafin ṣe jẹ ipe Ọlọrun ti ko si lanfani lati wo ipele igbesẹ mii ti oun gbe laye.

Adedoja Adeyemi
Adedoja Adeyemi