"Ẹ máà bínú bàbá,"- King Mitchy tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Ooni Ile Ifẹ

Aworan King Mitchy lapa osi, ti Ọọni Ile Ifẹ wa lapa ọtun

Oríṣun àwòrán, @king__mitchy/ Palace of Ooni Ile Ife

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajumọ lori ayelujara, Mitchell Mukoro ti ọpọlọpọ eeyan mọ si King Mitchy ti tọrọ aforijin ita gbangba lọwọ Kabiyesi Ọ̀ọni Ile Ifẹ Ọba Adeyẹye Ogunwusi pe oun tọrọ aforijin fun fifa orukọ rẹ wọ ọrọ kan to kan kaakiri ayelujara laipẹ yii.

King Mitchy ni oun kunlẹ fun oriade naa pẹlu ẹbẹ lẹyin ti oun ronu jinlẹ lori ihuwasi oun lati da orukọ ọbalaye naa ninu ọrọ edeaiyede kan to waye laarin oun atawọn gbajumọ ori ayelujara kan.

"Ẹ maa binu si mi fun bi mo ṣe gbe orukọ yin wọ inu ọrọ yii, ẹ maa binu baba,"

Bakan naa ni gbajumọ ori ayelujara naa tun tọrọ aforijin lọwọ ọmọ aarẹ Tinubu, Seyi Tinubu fun ohun to pe ni 'fifi iwọsi' lọọ ni ita gbangba.

"Mo fẹ ki o mọ pe mi o dẹyẹsi awọn atilẹyin rẹ fun mi."

Bakan naa ni Mitchy tun tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ Naijiria ati awọn ilumọọka ori ayelujara bii VeryDarkMan.

Ki lo ṣẹyẹ ṣaaju?

Ni ọsẹ melokan sẹyin ni iroyin gba ori ayelujara kan nigba ti King Mitchy kede pe oun ti tun awọn ile ẹkọ kan ṣe laarin ọsẹ mẹfa, to si n sọ pe ayipada to ye kooro le waye ni kiakia niwọn igba ti wọn ba ṣe e pẹlu ọkan ijolootọ.

Awọn eeyan woye nigba naa pe o seese ko jẹ pe VeryDarkMan ti oun naa jẹ ilumọ̀ọka lori ayelujara lo n sọ̀ oko ọrọ si. VeryDarkMan pẹlu naa da ọrọ pada fun un to si fi ẹsun kan an pe wọn n lo o ni lati fọnrere ijọba Tinubu.

Bakannaa lo tun ṣafihan ọrọ ajọsọ kan to ni oun ati Ọọni Ile Ifẹ ni to si n tọka sii pe "koda ọba yii'' ti kan si oun.

Ọrọ yii fa ọpọlọpọ awuyewuye lori ayelujara, to si tun mu ki ọpọ da ẹnu atẹ kọ arabinrin naa fun didẹyẹsi ọbalaye naa.

Awuyewuye naa tilẹ tun wa gbilẹ sii nigba ti VeryDarkMan naa wa fi ẹsun kan pe ọmọ aarẹ Naijiria, Seyi Tinubu pe oun lo n se agbodegba fun awọn iṣẹ ẹlẹyinju aanu gbogbo ti Mitchy n ṣe.

Ki lo de ti King Mitchy ti wọn kede pe o ti ku, tun ṣe jinde?

KIng Mitchy wọ aṣọ pupa ninu aworan yii.

Oríṣun àwòrán, @king__mitchy

Ọrọ naa wa gba ibomiran yọ nigba ti Mitchy farahan lori fọran ayelujara ti o si n gbe nnkan to fẹ fara jọ majele mu. Awọn eeyan to n wo fọnran naa ni yajoyajo n rọọ.

Ko pẹ pupọ lẹyin rẹ ni awọn alamojuto rẹ sọ pe o ti jade laye.

Wọ̀n ni o jade laye nile iwosan Prime Care Hospital nilu Abuja nibi ti wọn ni awọn gbe e lọlẹyin nnkan to gbe mu loju fọnran ti awọn araalu ri.

Amọṣa nigba to tun ya lawọn alakoso rẹ tun sọ ọ loju opo ayelujara Instagram rẹ pe ẹni ti awọn kede ṣaaju pe o ti ku tun ti wa laaye o.

"Michelle ti n gbadun bayii,"

Ṣaaju ki wọn to kede eyi ni ile iwaosan ti wọn sọ pe o ku si ti sare pariwo sita pe awọn ko fi igba kankan gba Mitchy gẹgẹbi alaisan ni ileewosan awọn, bẹẹni ko ku sibẹ rara.

"Irọ nla ni iroyin to n lọ kiri pe Omidan Mukoro Mitchele, ti ọpọ mọ si King Mitchy ku si ile iwosan wa niluu Abuja."

Ki ni Seyi Tinubu sọ si ọrọ naa ṣaaju?

Aworan Seyi Tinubu

Oríṣun àwòrán, Seyi Tinubu/instagram

Bakan naa ni Seyi Tinubu to jẹ ọmọ Aarẹ Naijiria, Ahmed Bọla Tinubu pẹlu ti gbe atẹjade kan sita pe irọ ni pe oun ati VeryDarkMan ati King Mitchy ni aawọ kankan.

Iroyin ti kọkọ gbe e pe VeryDarkMan n lọgun pẹlu ẹsun è Seyi Tinubu ati King Mitchy n dukoko mọ oun.

O ni iranwọ fun iṣẹ ẹyinju aanu Mitchy nikan loun ṣe, ko si ajọṣepọ idakọnkọ kankan pẹlu rẹ.

O fi ẹsun kan VeryDarkMan pe o n fi ọrọ ti ko kan oun fi ta ẹrẹ si aṣọ ala oun.