Ìgbà wo ni sísọ̀rọ̀ nípa ogun America- Israel àti Iran di ìwà ọ̀daràn ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, X Multiple
Ẹgbẹ ajafẹtọọ ọmọniyan ti a mọ si Amnesty International ti ke gbajare lorii bi awọn alaṣẹ ilẹ Naijiria ṣe fọwọ ofin mu awọn ọmọ orilẹede yii to ti sọrọ nipa ogun to n lọ lọwọ lagbegbe Middle East.
Iroyin sọ pe ninu ọsẹ yii, ẹka Department of State Security (DSS) nawọ gan awọn ọdọkunrin meji kan ni Kaduna, lori ohun ti wọn kọ soju opo ayelujara nipa ogun Iran ti America ati Israel bẹrẹ.
Ninu atẹjade Amnesty ni wọn ti ni awọn eeyan to lodi si America ati Israel ni awọn DSS n mu.
Wọn fi kun un pe igbẹsẹ ti wa lati gbe awọn ti wọn mu naa lọ si kootu lori ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ rara.
Ẹgbẹ naa sọ pe igbesẹ iru eyi yoo pa ohun mọ agogo awọn araalu lẹnu lati sọrọ ni.
Amnesty International koro oju si bi wọn ṣe mu awọn ọdọ meji naa, pẹlu alaye pe ọkan ninu wọn ko tilẹ ti i foju kan ẹbi rẹ tabi lọọya rẹ latigba ti wọn ti fofin mu un.
Awọn wo ni wọn mu?
Latigba ti iroyin awọn ti ijọba fofin mu yii ti gbode ni ọpọ eeyan lorilẹede Naijiria ti n koro oju si I, ti wọn si n pe fun itusilẹ awọn eeyan naa.
Gẹgẹ bi awọn ẹka iroyin abẹle ṣe ro o, ọkunrin kan, Sani Buhari to gbajumọ loju opo X, tawọn eeyan si mọ si Waspapping, wa lara awọn ti wọn mu nipinlẹ Kaduna lọjọ Ẹti to kọja.
Ṣaaju ni wọn si ti kọkọ mu ọkunrin kan ti wọn pe orukọ tiẹ ni Abubakar Adamu (Abbakar Affan ni wọn mọ ọn si loju opo X).
Ni ti Sani Waspapping, BBC gbọ pe wọn fofin mu un lẹyin ti olu ileeṣẹ US sọrọ lori awọn ohun to n kọ soju opo X rẹ, titi kan bo ṣe n fi han pe oun faramọ Iran, to si n tako America ati Israel.
Ṣugbọn a ko le fidi ohun pato to kọ to fa mimu rẹ mulẹ.
Bakan naa lo ri fun Abubakar Adamu, (Abbakar Affan), lẹyin to gbe ọrọ kan jade loju opo X rẹ nipa ogun Middle East ni wọn mu un ni Kaduna.
Awọn iroyin abẹle royin pe DSS gbe Affan lọ sile ẹjọ giga ijọba apapọ ni Kaduna, wọn ni atẹjiṣẹ rẹ to fi n pe fun pipa olori ilẹ Israel, Benjamin Netanyahu, le da rogbodiyan agbaye to le kan Naijiria silẹ.
Gẹgẹ bi oṣiṣẹ DSS; Jones Gabriel ṣe wi, atẹjisẹ naa le da ogun iru ti Israel ati Iran silẹ.
Ajọ naa tun sọ fun kootu pe ki wọn ma ṣe fi aaye beeli silẹ fun un rara, nitori ẹṣẹ to ṣe lagbara pupọ, to si le ran an lọ si ẹwọn gbere bi wọn ba dajọ rẹ tan.
BBC kan si ajọ DSS, amọ wọn ko fesi.
Ibi to de duro
Ohun ti BBC ri gbọ ni pe wọn ti fi Sani Waspapping silẹ, amọ o wa ni igbele (House arrest).
Bakan naa ni wọn ti gba foonu rẹ, wọn si ti fofin de e lati ma ṣe lo oju opo ayelujara.
Awọn ọrẹ rẹ kan naa to sunmọ ọn gidi ko gbọdọ da si ọrọ yii bi aṣẹ atẹjade naa ṣe wi.
BBC kan si awọn ẹbi Waspapping kan, wọn si sọ fun wa pe awọn ko le sọrọ le e lori.
Ṣugbọn lasiko ti a n kọ iroyin yii, DSS ko ti i fi atẹjade kankan sita.
Ni ti Affan, ko ti I si iroyin nipa rẹ yatọ si ti kootu ti wọn gbe e lọ.
Amọ ajọ Amnesty International kọminu si eyi, wọn ni bii ẹni to n pa ohùn mọ agogo awọn eeyan lẹnu ni.


























