Àlàyé rèé lórí ìdí tí Nàíjíríà fi bọ́ sí ipò kẹrin láti ipò kẹfà, nínú àwọn orílẹ̀èdè tí ìgbésùnmọ̀mí ti gbilẹ̀ ní àgbáyé

Ikọ awọn agbebọn to gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Alamy

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Orilẹede Naijiria ti wa nipo kẹrin lagbaye lọdun 2025 ninu awọn orilẹede ti iwa igbesunmọmi ti peleke,

Igbelewo ọlọdọọdun nipa bawọn orilẹede lagbaye ti gbewọn si nidi iwa igbesunmọmi, global terrorism index (GTI) 2025 lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan.

Iroyin naa ni awọn ikọlu to n waye ni Naijiria ti le si pẹlu ida mẹtalelogoji ta ba se odiwọn rẹ si awọn ikọlu to waye lọdun 2024.

Orilẹede Pakistan lo n lewaju akọsilẹ naa, ti orilẹede Burkina Faso si se ipo keji, nigba ti orilẹede Niger se ipo kẹta.

Naijiria si lo fi ipo meji lọ soke si, tori o kuro lati ipo kẹfa to wa tẹlẹ lọdun 2024, lọ sipo kẹrin laarin ọdun 2024 si 2025

Agbekalẹ iroyin naa, to se igbelewọn awọn ipa ti iwa igbesunmọmi n ko laarin awọn orilẹede agbaye lọdun 2025 ni ibudo to wa fun ọrọ aje ati alaafia, Institute for Economics & Peace (IEP), ti ibujoko rẹ wa nilu Sydney, lorilẹede Australia, gbe jade.

Gẹgẹ bi iroyin naa se wi, awọn isẹlẹ igbesunmọmi mọkanlelaadọsan (171) lo waye nilẹ Naijiria lọdun 2025 nikan.

Eyi si fi ida mẹtalelogoji le si awọn isẹlẹ igbesunmọmi to waye lọdun 2024, tii se ọgọfa pere.

Naijiria si lo fi ipo meji lọ soke si, tori o kuro lati ipo kẹfa to wa tẹlẹ lọdun 2024, lọ sipo kẹrin laarin ọdun 2024 si 2025.

Iroyin naa ni awọn ikọ afẹjẹwẹ ISWAP ati Boko Haram si lo wa nidi awọn ikọlu asekupani to waye lọdun 2025.

Ikọlu agbesunmọmi sawọn araalu jẹ isẹlẹ mẹtadinlaadọrin, apapọ awọn eeyan to ku tori ikọlu agbesunmọmi lọdun 2025 si jẹ ẹẹdẹgbẹrin ati aabọ

Awọn araalu si lo fori sọta awọn ikọlu yii julọ lọdun 2025, ti ikọlu sawọn araalu si jẹ mẹtadinlaadọrin.

Amọ ikọlu sawọn ọmọ Ologun lo ko ida mọkandinlogun, gẹgẹ bii akọsilẹ naa se safihan rẹ.

"Awọn eeyan to n ku latipasẹ ikọlu awọn agbesunmọ mi si lo n peleke si pẹlu ida mẹrindinlaadọta, ti apapọ awọn eeyan to ku lọdun 2025 si jẹ ẹẹdẹgbẹrin ati aabọ.

Iye awọn eeyan to ku yii si lo tii pọ julọ lati ọdun 2020, eyi ko si sẹyin rogbodiyan abẹle ati aawọ to wa laarin ikọ agbesunmọmi ISWAP ati Boko Haram."

Akọsilẹ naa tun salaye pe eeyan ẹẹdẹgbẹrin ati aabọ lo ku, ti eeyan mọkanlelaadọtan si farapa ninu ikọlu awọn agbesunmọmi nikan lọdun 2025.

Amọ eeyan ẹgbẹrun mejila ati aabọ lo wa ni akọsilẹ pe wọn ba isẹlẹ igbesunmọmi lọ lati ọdun 2007.

Ibudo ti ado oloro ti dun, ọmọ ologun kan n rin kọja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ oselu ADC gba ijọba Tinubu ni gbolohun lori ipo kẹrin ti Naijiria wa laarin awọn orilẹede ti iwa igbesunmọmi ti rẹsẹ walẹ

Wayi o, ẹgbẹ oselu African Democratic Congress (ADC) ti woye pe bi orilẹede Naijiria ti se ipo kẹrin ninu awọn orilẹede agbaye ti iwa igbesunmọmi ti sọsẹ julọ, lo fidi rẹ mulẹ pe ijọba aarẹ Bola Tinubu ti kuna lati daabo bo orilẹede Naijiria.

Atẹjade kan ti akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oselu ADC, Bolaji Abdullahi fisita, tọka si pe ipo kẹrin ti Naijiria gbe naa buru jai.

Abdullahi ni iwadii yii lo se afihan pe isejọba ti dojude dipo ko jẹ asise awọn Ologun.

"Akọsilẹ naa, eyi to waye lasiko ti isẹlẹ ọpọ ado oloro to bu nilu Maiduguri waye, lo safihan esi to n ba ni ninujẹ lori eto aabo Naijiria pe o mẹhẹ.

Eyi si lo safihan ijakulẹ ijọba APC ti aarẹ Bola Tinubu n dari ninu ilakaka rẹ lati dabobo orilẹede yii."

Abdullahi tun koro oju si bi awọn adari Naijiria ko se si nile lasiko yii ti idarudapọ n waye lorilẹede yii.

Àkọlé fídíò, Kí ni àbẹ̀wò ààrẹ Tinubu sí UK túmọ̀ sí?

Òde kò dára fún ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀! Ọ̀pọ̀ agbébọn tó yawọ ibùdó ológun ní Borno fi ikú ṣe ìfà jẹ, ológun pa olórí mẹ́ta àti ọgọ́rin ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram

Awọn ohun ti ileesẹ ologun bajẹ

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria to n gbogun ti iwa igbesunmọmi, ti wọn n pe ni Hadin Kai, ti kede lọjọru pe awọn kọju oro sawọn agbebọn Boko Haram ni agbegbe Mallam Fatori, ni ijọba ibilẹ Abadam nipinlẹ Borno.

Bakan naa ni wọn tun pa olori awọn ikọ agbebọn naa mẹta pẹlu awọn ọmọ ikọ afẹjẹwẹ naa bii ọgọrin.

Eyi wa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileesẹ ologun, ẹka ikọ ologun alajumọse Hadin Kai, Sanni Uba, fi sita pẹlu orukọ awọn olori ikọ agbebọn naa.

Orukọ awọn olori ikọ agbebọn naa ni Abdulrahman Gobara, Mallam Ba Yuram, ati Abou Ayyuba.

Awọn si ni olori agbebọn to lewaju ikọ ọpọ ado oloro to bu ni Maiduguri laipẹ yii.

"Awọn agbebọn ya wọle si ibudo awọn ologun pẹlu ẹsẹ, wọn ju ado oloro si awọn ọmọ ologun"

Awọn agbebọn yoku ti ẹmi tun bọ lẹnu wọn ni Zarkawi, Ba Bunu, Rawa Fannami, Abowor Suwurti, Bulama Mil, Abu Aisha, Suleimana, Abu Rijal, Abu Ali, Abba Gana Kawiyya, ati Ahmodu Hirasama.

Atẹjade naa ni, "Ikọ ologun Joint Task Force (North East) Operation Hadin Kai (OPHK) ni owurọ Ọjọru ṣẹgun ikọlu Boko Haram ni agbegbe Mallam Fatori ni Sector 3."

O ni awọn agbebọn naa ni wọn ya wọle si ibudo awọn ologun pẹlu ẹsẹ, ti wọn si n ju ado oloro si awọn ọmọ ologun, ṣugbọn agbara ju agbara lọ.

"Ikọ ologun fi isẹlẹ naa ṣe oju ni alakan fi n sọ ori, ti wọn si gbe ija pada ikọ agbebọn ologun yii," atẹjade naa ṣalaye.

O fikun pe o kere tan, ikọ ologun ṣekupa awọn agbebọn to le ni Ọgọrin ni iye.

"Ologun ri ọpọ ohun ija gba lọwọ awọn agbebọn naa bii ọta ibọn, ibọn AK 57 to jẹ 52, ibọn PKT mẹjọ, RPG tubes meje, General Purpose Machine Guns (GPMGs) marun un"

Sanni tẹsiwaju pe, ikọ ologun ri ọpọlọpọ ohun ija gba lọwọ awọn agbebọn naa bii ọta ibọn, ibọn AK 57 to jẹ 52, ibọn PKT mẹjọ, RPG tubes meje, General Purpose Machine Guns (GPMGs) marun un.

O si o le ni ẹgbẹrun mẹta assorted 7.62mm ammunition, ado oloro RPG mọkanlelogun, ibọn ibilẹ mẹsan an, ẹrọ ibaraẹnisọrọ ati awọn nnkan ija mii ti awọn ologun tun ti gba lọwọ awọn agbebọn naa.

Sanni wa fi da awọn araalu loju pe, eto aabo ni adugbo Mallam Fatori ati agbegbe rẹ yoo lekun si, to si rọ awọn araalu pe ki wọn ni ifura ni gbogbo igba .

Bakan naa ni ileeṣẹ ologun kan sara si awọn ọmọ ologun Naijiria fun iṣẹ nla ti wọn ṣe lati fi koju awọn agbebọn Boko Haram.

Ni ọjọ Aje ọsẹ yii ni aìmọye ado oloro iku tí bu niluu Maiduguri, tii ṣe olu ìlu ipinlẹ Borno, to si gbemi ọpọlọpọ eeyan.

Iṣẹlẹ ibugbamu naa waye niwaju ile iwosan ẹkọṣẹ isegun fasitì Maiduguri ati lawọn ọja nla meji ti wọn n pe ni ọja Post Office ati ọja ọjọ Mọnde.