Kókó ohun tí Mojtaba Khamenei sọ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó di olórí Iran

Mojtaba Khamenei wé láwàní dúdú sórí, ó wọ ìgò ojú, ó ń wo ilẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olórí orílẹ̀ èdè Iran tuntun, Mojtaba Khamenei ti sọ pé orílẹ̀ èdè náà yóò tẹ̀síwájú láti máa ti Strait of Hormuz èyí tó jẹ́ òpópónà tó ṣe pàtàkì sí gbígbe epo rọ̀bì lọ́jà àgbáyé.

Mojtaba sọ èyí nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀ láti ìgbà tó ti gba ipò olórí orílẹ̀ èdè náà lọ́jọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹta, ọdún 2026.

Títi Strait of Hormuz ló ti ń jẹ́ ohun ìkọnilóminú lọ́jà àgbáyé nítorí ó ń ṣe ìdíwọ́ fún gbígbé epo rọ̀bì, bí ó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èpò rọ̀bì ló ń gba ọ̀nà náà kọjá lọ sáwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé.

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Mojtaba yóò sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ṣekúpa bàbá rẹ̀, Ayatollahi Ali Khamenei lọ́jọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejì nígbà tí Amẹ́ríkà àti Israel pawọ́pọ̀ ṣe ìkọlù sí Iran.

Mojtaba ni ọmọkùnrin kejì tí Ali Khamenei bí, tí ìgbàgbọ́ sì ti wà tipẹ́ pé òun ló máa gba ipò lọ́wọ́ bàbá rẹ̀.

Yàtọ̀ sí bàbá rẹ̀, ìkọlù Amẹ́ríkà àti Israel náà ṣekúpa ìyá àti ìyàwó rẹ̀, tí àwọn kan sì sọ ppé òun náà ṣèṣe nínú ìkọlù náà.

Kókó ohun tó sọ

  • Títi Strait of Hormuz

Mojtaba sọ fún àwọn ọmọ ogun Iran láti túnbọ̀ tẹ̀síwájú pẹ̀lú Strait of Hormuz tí wọ́n tì pa. Títi òpópónà náà ti sọ gbogbo àgbáyé sí hílàhílo, tí owó epos ì ti gbówó lórí káàkiri àgbáyé.

Títi Strait of Hormuz jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì tí Iran le lò lórí ogun tó ń lo láàárín òhun, Amẹ́ríkà àti Israel.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ṣèkìlọ̀ fún Iran pé wọn kò gbọdọ̀ ti Strait of Hormuz.

Amẹ́ríkà ní kò dín ní àdó olóró mẹ́wàá tí Iran lò láti fi gbẹ́ ilẹ̀ sínú strait náà tí àwọn ti bàjẹ́.

  • Wíwà ní àlááfíà pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ Lárúbáwá míì

Olórí tuntun fún Iran náà sọ pé àwọn ṣì ń dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tó yí àwọn ká ṣùgbọ́n tó gba gbogbo lámọ̀ràn láti ti àwọn iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tó wà ní orílẹ̀ èdè wọn pa kí àlááfíà le túnbọ̀ máa jọba.

Láti ìgbà tí Amẹ́ríkà àti Israel ti ṣe ìkọlù sí Iran ni Iran náà ti ń ju àdó olóró sáwọn ibùdó Amẹ́ríkà tó wà ní àwọn orílẹ̀ èdè bíi Qatar, UAE, àti Bahrain.

Ní ọjọ́rú ni àwọn orílẹ̀ èdè dìbò láti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù Iran sáwọn orílẹ̀ èdè náà.

Ṣíṣe ìtẹ̀síwájú ìkọlù sáwọn iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà

Mojtaba Khamenei sọ pé orílẹ̀ èdè òun yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ìkọlù sáwọn iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tó wà ní àwọn orílẹ̀ èdè tó yí àwọn ká.

Amẹ́ríkà ní àwọn ibùdó ológun tó pọ̀ láwọn orílẹ̀ èdè Gulf, tí Iran sì ti ń ṣèkọlù sí wọn láìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀.

  • Gbígba ẹ̀san

Lórí àwọn èèyàn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn lórí ìkọlù náà, Mojtaba sọ pé gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ Iran tí wọ́n ta sílẹ̀ ni àwọn máa gbẹ̀san rẹ̀.

Ó wòye pé ìkọlù Minab, níbi tí Amẹ́ríkà ti ṣe ìkọlù sí ẹ̀gbẹ́ ilé ẹ̀kọ́, èyí tó ṣokùnfà ikú èèyàn 168 tó fi mọ́ àwọn ọmọdé 110 ni Mojtaba ní àwọn máa gbẹ̀san rẹ̀.

Iran ní US ló ṣe ìkọlù sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣùgbọ́n Akọ̀wé ètò ààbò Amẹ́ríkà, Pete Hegseth sọ fún BBC pé àwọn máa ṣe ìwádìí ìkọlù náà.

  • Kíkan sáárá sí Hezbollah

Mojtaba Khamenei dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun tó dúró tì wọ́n ní Yemen, Hezbollah ní Lebanon àtàwọn ikọ̀ míì ní Iraq.

  • Bíbéèrè fún gbà má bínú

Mojtaba Khamenei sọ pé àwọn máa bèèrè fún ẹ̀bùn gbà má bínú fún gbogbo àwọn àdánú tí àwọn kojú lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ọ̀tá wọn.

Ó ní tí wọ́n bá kọ̀ pé àwọn kò ní san-án, àwọn máa mú ohun ìní wọn tó tó iye nǹkan tí àwọn pàdánù.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ń pè fún àlááfíà láàárín àwọn àtàwọn orílẹ̀ èdè tó yí àwọn ká, síbẹ̀ àwọn kò ní dáwọ́ ìkọlù sáwọn ibùdó Amẹ́ríkà láwọn orílẹ̀ èdè náà dúró.

Ṣáájú ni aṣojú Iran sí Cyprus, Alireza Salarian sọ fún ìwé ìròyìn The Guardian pé òun gbọ́ pé Mojtaba ṣèṣe ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, tí òun sì rò pé ó wà nílé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú, tí òun kò sì lérò pé ó máa sọ̀rọ̀.