Àwọn olùwọ́de lu ìgboro Aba láti wọ́de pè fún ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Nnamdi Kanu/BBC
Biba ni ero pọ loju ọna niluu Aba, ipinlẹ Abia, lowurọ Ọjọbọ, ọjọ kejila, oṣu Kẹta ọdun 2026 yii. Ohun ti wọn n ṣe naa ni iwọde to n pe fun itusilẹ Nnamdi Kanu, olori ẹgbẹ IPOB tijọba Naijiria ju si ẹwọn gbere.
Gẹgẹ bi BBC Igbo ṣe fidi ẹ mulẹ, aago mẹsan-an aarọ ko ti I lu ti awọn oluwọde naa ti tu si oju opopo pẹlu awọn akọle ọlọkan-o-jọkan ti wọn fi n beere itusilẹ Nnamdi Kanu.

Bi awọn kan ṣe n fi ẹsẹ rin ni awọn kan wa lori alupupu, ti wọn si pọ gidi.
Awọn oluwọde naa sọ pe o yẹ kijọba Naijiria fi Nnamdi Kanu silẹ lẹyẹ-o-sọka, wọn ni ahamọ kọ lo yẹ ko wa rara.
Omoyele Sowore, Emmanuel Kanu darapọ mọ iwode naa
Lara awọn eeyan to darapọ mọ iwọde naa ni ondupo aarẹ Naijiria ni 2023, to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan; Omoyele Sowore.
Bakan naa ni Emmanuel Kanu, ẹni ti I ṣe aburo fun Olori ẹgbẹ IPOB to wa lahamọ naa darapọ mọ iwọde ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, Nnamdi Kanu ni ijọba apapọ Naijiria ju si ẹwọn gbere, lẹyin ti Adajọ James Omotosho da ẹjọ rẹ to si ni o jẹbi awọn ẹsun ọlọkan -o-jọkan ti wọn fi kan an.
Lara ẹsun ọhun si ni jijẹ agbesunmọmi wa.
Olutẹle Nnamdi Kanu ni mi, olutẹle idajọ ododo si ni mi pẹlu- Sowore

Nigba to n sọrọ nipa idi to fi darapọ mọ iwọde naa, Omoyele Sowore to wa lara awọn to pe fun idasilẹ Kanu lẹyin idajọ naa sọ pe:
" Olutẹle Nnamdi Kanu ni mi, olutẹle idajọ ododo si ni mi pẹlu.
"A n pe Aarẹ Bola Tinubu lati fi Nnamdi Kanu silẹ bayii."

"A kilọ fun wọn tẹlẹ naa ki wọn too lo Adajọ James Omotosho lati ran Nnamdi Kanu lọ sẹwọn. "
Sowore sọ pe atilẹyin loun wa ṣe fun Kanu nibi iwọde yii, oun ko si ni i pada, afi bi wọn ba fi olori IPOB to n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra naa silẹ."


























