Ó ti yá jù fún kóòtù láti pàṣẹ pé mi ò lè dupò gómìnà mọ́- Aiyedatiwa

Gomina ipinlẹ Ondo,Lucky Orimisan Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Lucky Aiyedatiwa/ X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Lẹyin idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo to ni Gomina ipinlẹ naa; Lucky Aiyedatiwa, ko le dupo gomina lẹẹkan si i lẹyin ọdun mẹjọ ti ofin la kalẹ, Aiyedatiwa ti fesi pe ipinnu naa ti ya ju, bẹẹ lo jẹ ohun to le ṣi oju eeyan kuro lara oṣelu.

Ọjọbọ ana ti idajọ naa waye ni Aiyedatiwa ti fesi pada, nigba to n sọrọ lori eto ileeṣẹ amohunmaworan Channels kan.

Gomina Aiyedatiwa sọ pe:

"Asiko yii kọ lo yẹ ki ọrọ bẹrẹ lori agbekalẹ ibo ọdun 2028,(off-cycle governorship election), ṣebi awọn araalu ṣẹṣẹ fi ibo wọn gbe mi wọle laipẹ yii.

"Eyi ti ya ju. Ki lo de ti wọn ko duro di 2027 tabi nigba ti alakalẹ ilana idibo yoo ba fi jade ni ibẹrẹ ọdun 2028?

"Boya nigba ti yoo ba fi di igba yẹn, mo le ti maa ro o boya mo le dije tabi bẹẹ kọ."

Gomina Aiyedatiwa tẹsiwaju pe iru igba yẹn ni oun le maa ronu awọn nnkan kan ti ofin sọ.

O fi kun un pe ohun to jẹ oun logun ni boun yoo ṣe ṣiṣẹ ti awọn oludibo gbe le oun lọwọ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2024.

"Ìbò ọjọ iwaju ko tiẹ si lọkan mi tẹlẹ''

Ni itẹsiwaju alaye rẹ lori idajọ kootu ọhun, Gomina Aiyedatiwa sọ pe oun ko tilẹ ni I lọkan lati kopa ninu idibo kankan lọjọ iwaju.

"Idibo to lọ ni irọwọrọsẹ to si yanju ni mo kopa ninu ẹ lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kọkanla, ọdun 2024. Fun idi eyi, ko ti i pẹ rara. Mi o ronu ibo kankan ju bi ma a ṣe ṣiṣẹ ti wọn gbe le mi lọwọ lọ.

"Ko si lero ọkan mi lati gbegba ibo kankan lọjọ iwaju, nitori eto eto ni gbogbo ẹ."

Aiyedatiwa sọ pe loootọ loun mọ pe ofin sọ pe gomina ko le lo ju ọdun mẹjọ lọ, ṣugbọn oun ko tiẹ ti i ro bi yoo ṣe kan oun.

Bakan naa lo ṣapejuwe idajọ kootu yii bii ohun to kan le yi oju oun pada kuro ninu oṣelu, lẹyin awọn ogun oṣelu toun ti koju tẹlẹ.

O ni ko sẹni kan to n dọdẹ oun ninu oṣelu, bẹẹ loun ko si fipa mu awọn ọmọ ẹgbẹ lati kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC, eyi wulẹ waye bẹẹ ni.

Kò lè ṣẹlẹ̀! Iléẹjọ́ ní Lucky Aiyedatiwa, gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo kò lẹ́tọ̀ọ́ láti díje fún sáà míràn mọ́

Aworan Gomina Lucky Aiyedatiwa pẹlu ẹrọ gbohungbohun lọwọ ọtun rẹ, igbalẹ idanimọ ẹgbẹ oṣelu APC lọwọ osi lasiko ipolongo ibo kan.

Oríṣun àwòrán, Lucky Orimisan Aiyedatiwa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ kan ni ilu Akurẹ ti gbe idajọ kalẹ pe gomina ipinlẹ naa, Lucky Ayedatiwa ko ni le dije dupo saa miran mọ gẹgẹbi gomina ipinlẹ Ondo.

Onidajọ̀ Toyin Bolaji Adegoke to gbe idajọ naa kalẹ ni Ọjọbọ pe iwe ofin Naijiria tọdun 1999, gẹgẹbi awọn atunṣe to ti waye lori rẹ ko fi aye kankan silẹ nibi ti aarẹ,igbakeji aarẹ, gomina ati igbakeji rẹ yoo lo ju ọdun mẹjọ lọ nipo.

Ni ọ̀jọ kẹtadinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2024 ni wọn kọkọ ṣebura fun Aiyedatiwa lati pari saa gomina igba naa, Rotimi Akeredolu to ku lẹyin aisan nigba naa gẹgẹbi igbakeji rẹ.

Ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu keji ọdun 2025 ni wọn tun bura fun un pada fun saa ọlọdun mẹrin lẹyin to bori ibo sipo gomina ipinlẹ Ondo to waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla ọdun 2024.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC kan, Dokita Akin Egbuwalo lo wa wọ oun ati igbakeji rẹ, Ọmọwe Ọlayide Adelami ati ẹgbẹ oṣelu APC lọ si ileẹjọ lati pẹjọ lori ẹtọ rẹ lati dije fun saa miran nipo gẹgẹbi gomina ni ipinlẹ Ondo.

Kí ni ìrètí Aiyedatiwa láti du ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo fún sáà míì?

 Lucky AIyedatiwa lasiko ipolongo ibo

Oríṣun àwòrán, Lucky AIyedatiwa

Ana ọjọ Aje ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ilu Abuja gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ kotẹmilọrun ti gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa pe tako aṣẹ ilẹ ẹjọ giga ilu Akure.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun naa sọ pe ile ẹjọ giga ilu Akure ko ṣe aṣiṣẹ lori bo ṣe sọ pe ẹni to pe aiyedatiwa lẹjọ, Akindele Egbuwalo, lẹtọọ lati ṣatunṣe si awọn iwe ipẹjọ rẹ.

Adajọ Uchechukwu Onyemenam ni gomina Aiyedatiwa ninu ẹjọ kotẹmilọrun rẹ kuna lati fidi rẹ mulẹ pe ile ẹjọ giga ilu Akure ko ṣe daadaa si oun ati pe ko fun oun laye lati gbọ tẹnu oun bo ṣe gba ẹbe Egbuwalo wọle.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun naa wa sọ pe ẹjọ ti Aiyedatiwa pe ko lẹsẹ nilẹ, o si da ẹjọ ọhun nu.

Ile ẹjọ kọtẹmilọrun ọhun tun ni ki Aiyedatiwa san miliọnu meji naira fun Akindele Egbuwalo eyii ti yoo jẹ lara owo to na fun igbẹjọ kotẹmilọrun naa.

Ki ni itumọ idajọ yii?

Lati mọ ohun ti idajọ yii tumọ si ati bo ṣe kan Aiyedatiwa ninu eto idibo gomina ipinlẹ ti yoo waye nipinẹ Ondo, BBC Yoruba kan si agbẹjọro kan, Ebiwanno Omolade.

Omolade ni idajọ to waye lana yii ko ni nnkankan lati ṣe lori boya Aiyedatiwa yoo lanfani lati dije ninu eto idibo to n bọ tabi bẹẹ kọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, idajọ to waye yii ni wọn n pe ni "interlocutory injuction" to n tumọ si idajọ to waye ki ile ẹjọ to ṣedajọ lori ọrọ gan to n ja nilẹ.

Ninu alaye rẹ, o ni idajọ to waye da lori pe boya awọn to pe ẹjọ ṣaju le ṣatunṣe si ẹjọ naa, ko si ni nnkankan lati ṣe lori boya Aiyedtiwa le dije tabi bẹe kọ.

O ni "Ọrọ pe Aiyedatiwa le dije, ko le dije, ko ti si idajọ kankan lati ile ẹjọ kankan lori rẹ. Ko tii si idajọ ori rẹ lọwọ yii.

"Idajọ ti wọn gba yii, ẹjọ ninu ẹjọ ni, kii ṣe idajọ lori boya yoo le dije tabi bẹẹ kọ.

"Ẹjọ lori boya yoo le dije ṣi wa nile ẹjọ, ẹjọ naa ṣi wa niwaju adajọ lọwọ yii."

Ki ni ohun to kan fun Aiyedatiwa bayii?

Agbẹjọro naa ni nnkan meji ni Aiyedatia le ṣe bayii.

Ohun kinni ni pe ko lọ si ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lati pe ẹjọ tako idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to waye lana ọjọ Aje.

O ṣalaye pe ọjọ mẹrinla pere ni gomina ọhun ni lati pe ẹjọ kotẹmilọrun nile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ọhun.

Igbesẹ keji to le gbe gẹgẹ bii agbẹjọro naa ṣe sọ ni pe ko pada siluu Akure fun itẹsiwaju ẹjọ akọkọ lori boya yoo le dije tabi bẹẹ kọ.

Sẹ Aiyedatiwa fẹ dije fun saa mii?

Aiyedariwa funra ti sọ pe oun ko tii sọ boya oun yoo dije tabi bẹẹ kọ, nitori naa ko yẹ ki awọn igbẹjọ yii waye rara.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin lopin ọsẹ niluu Akure, Aiyetiwa fidi rẹ mulẹ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko tii kede pe oun fẹ dije, oun yoo dije ti ofin ba faye gba oun.

Wayi o, bi awọn araalu kan ṣe n sọ pe ijọba Aiyedatiwa ko san awọn, lawọn mii n sọ pe irọrun ni ijọba rẹ ba de fun awọn.

Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn dájọ́ lórí ẹ̀tọ́ Aiyedatiwa láti dupò gómìnà Ondo fún sáà míì

Gómìnà Aiyedatiwa dé fìlà tí wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sí, ó ń wo ọ̀ọ́kán

Oríṣun àwòrán, Lucky Aiyedatiwa/Facebook

Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti ìlú Abuja ti gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Lucky Aiyedatiwa kò ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti dupò gómìnà ìpínlẹ̀ náà níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀.

Ṣáájú ni ilé ẹjọ́ gíga tó fi ibùjókòó sí ilú Akure, lọ́jọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ti kọ́kọ́ dájọ́ pé Aiyedatiwa kò lè dupò gómìnà ìpínlẹ̀ náà ṣùgbọ́n tí gómìnà pe ìdájọ́ náà ní ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn.

Nínú ìdájọ́ tí àwọn adájọ́ mẹ́ta fẹnukò gbé kalẹ̀ sọ pé ilé ẹjọ́ gíga náà ṣe ohun tó tọ́ nípa fífi ààyè gba Akindele Egbuwalot ó pe ẹjọ́ láàyè láti ṣe àtúnṣe sí ẹjọ́ tó pè.

Adájọ́ Uchechukwu Onyemenam tó ka ìdájọ́ náà síta sọ pé Aiyedatiwa kò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ẹjọ́ tó pè pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga jẹ́ títẹ ẹ̀tọ́ ohun mọ́lẹ̀ tàbí pé wọn kò fààyè gba òun láti ṣàlàyé ara òun.

Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà wá da ẹjọ́ náà nù, tí wọ́n sì ní kí gómìnà san owó ìtanràn mílíọ̀nù méjì náírà fún ilé ẹjọ́ lórí ẹjọ́ tó gbé síwájú àwọn.

Ṣáájú ni ilé ẹjọ́ náà ti kọ́kọ́ da ẹjọ́ tí Gómìnà Aiyedatiwa pè láti láti da àṣẹ ti ilé ẹjọ́ náà pa lọ́jọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní pè kí gbogbo ìgbẹ́jọ́ tó wà ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ìdádúró fún ìgbà kan ná.

Ilé ẹjọ́ ní àṣẹ náà jẹ́ ohun tó tọ́ lábẹ́ òfin fún wọn láti ṣe láti dá ààbò bo àwọn ìgbẹ́jọ́ tó wà níwájú rẹ̀.

Wọ́n wòye pé àsìkò tí àṣẹ náà fi máa jáde, wọ́n ti ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti Aiyedatiwa pè, tí wọ́n sì ṣe ohun tó tọ́ láti rip é ìgbẹ́jọ́ tó wà níwájú wọn kò di ohun àtẹ̀mẹ́rẹ̀.

Ilé ẹjọ́ ní bí Aiyedatiwa ṣe ni kí àwọn da àṣẹ tí àwọn pa lọ́jọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní náà nù túmọ̀ sí pé ó ní kí àwọn kó ọ̀rọ̀ àwọn jẹ ni.

Wọ́nn ní ìgbésẹ̀ tó yẹ fún Aiyedatiwa láti gbé ni kó pe ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà, ìyẹn Supreme Court.

Bákan náà ni wọ́n tún ní kó san owó ìtanràn mílíọ̀nù kan náírà fún bí ó ṣe ní kí àwọn gbé ìdájọ́ tí àwọn ti gbé sílẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan.