A fẹ́ ṣàfikún iná mọ̀nàmọ́ná tí à ń rà láti Naijiria, iná wọn ń ràn okòòwò àti lílò nílé wa lọ́wọ́ -Orílẹ̀èdè Togo

Oríṣun àwòrán, NAN
Orilẹede Togo ti fifẹ han lati ṣafikun odiwọn ina mọnamọna ti wọn ra lati Naijiria, nipasẹ ileeṣẹ Niger Delta Power Holding Company. (NDPHC).
Adari ileeṣẹ NDPHC, Jennifer Adighije, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku oni, lẹyin ajọsọ ọrọ pẹlu ikọ onina mọnamọna to wa lati orilẹede Togo.
Adari agba ileeṣẹ mọnamọna ilẹ Togo; Débo K'mba Barandao to lewaju ikọ naa, ṣalaye pe o ṣe pataki lati ṣafikun ina ti Togo n ra lati Naijiria, nitori iranlọwọ gidi lo n ṣe fun okoowo, lilo nile ati idagbasoke ilẹ Togo lapapọ.
O ni nnkan bii wakati 75 megawatt ni ina ti Togo n ko wọle lati Naijiria bayii, labẹ adehun ajọṣe to n pese ina naa.
" Ina ti a n ra lati Naijiria n ko ipa pataki ninu bi a ṣe n ni ina mọnamọna deede, o si n ran ọrọ aje wa lọwọ kaakiri Togo."
Barandao lo ṣalaye bẹẹ.
O fi kun un pe ina to n wa lati Naijiria naa ko wọn rara, o rọrun fun awọn ileeṣẹ ati awọn eeyan to n lo o nile lati ra a daadaa, titi kan awọn ileeṣẹ ijọba kaakiri Togo.
Barandao sọ pe awọn eeyan ti nilo ina ọba si i ni Togo, paapaa awọn ileeṣẹ , bẹẹ ni ijọba naa si tun fẹ ki ina kari.
"Ilana sisanwo bo ṣe yẹ yoo jẹ ko ṣee ṣe fun NDPHC lati tẹsiwaju ninu ajọṣepọ ọrọ ina mọnamọna."
Nigba to n fesi, ọga NDPHC, Jennifer Adighije, ṣalaye pe ileeṣẹ yii ti ṣetan lati so okun aṣepọ pẹlu awọn orilẹede alamuleti Naijiria le si i.
O ni awọn ṣetan lati ta ina fun awọn orilẹede to wa ni ẹkun Iwọ-Oorun Africa.
Adighije sọ pe siṣe eyi wa ni ibamu pẹlu Economic Community of West African States (ECOWAS) to n so okun ajọṣepọ le laaarin awọn orilẹede rẹ.
O fi kun un pe owo ni yoo jẹ ṣaa o. Bawọn Togo ba n fẹ ina bẹẹ, wọn yoo ṣetan lati ṣeto sisanwo bo ṣe yẹ.
"Ilana sisanwo bo ṣe yẹ yoo jẹ ko ṣee ṣe fun NDPHC lati tẹsiwaju ninu ajọṣepọ ọrọ ina mọnamọna."
Bẹẹ lo ni yoo mu ewu to rọ mọ fifi ina ọba ranṣẹ lati ilu kan si ikeji ku.


























