Àwọn afurasí agbébọn yín àdó olóró tí kò lóǹkà, ẹ̀mí 23 bọ́, 108 farapa

Oríṣun àwòrán, Vanguard Newspaper
Àìmọye àdó ikú tí bù nilu Maiduguri, tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Borno, tó sì gbemi ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.
Ọjọ Aje ana ni ìṣẹ̀lẹ̀ ibugbamu náà waye níwájú ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ isegun fásitì Maiduguri áti lawọn ọjà ńlá méji tí wọ́n ń pè ní ọjà Post Office àti ọjà ọjọ́ Mọnde.
Gẹ́gẹ́ bí olórí àjọ to n ṣètò ìdẹ̀rùn pajawiri nílẹ̀ wa, NEMA, Sirajo Abdullahi, se wi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lo forí sọta Ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọn sì ń gbà itoju lọ́wọ́ nile iwosan àmọ́ ó ní òun kò le sọ iye wọn ní pàtó.
Àmọ́ títí di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, kò tíì sí ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí kankan tó tíì kéde pé òun ló wà nìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Akọtun ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù àdó olóró yìí ló wáyé lásìkò yìí ti eto aabo mẹhẹ yíká Nàìjíríà nítorí ìkọlu àwọn agbébọn to n sọsẹ lápá àríwá ílẹ̀ wá.
Gomina Ìpínlẹ̀ Borno, Babagana Zulum ti bu ẹnu atẹ lu ìṣẹ̀lẹ̀ ibugbamu náà, pẹ̀lú àfikún pe ọwọ́ àwọn ológun to n dun àwọn agbésùnmọ̀mí nínú igbó Sambisa tí wọn wá, lo mú kí wọn máa jẹ aporo yìí.
"Ero ati àdúrà mi wa lara awon eniyan tó forí sọta ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, èyí tó burú jáì, tó sì jẹ ìwà ìkà ponbele."
Bakan naa, agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno, Nahum Daso Kenneth, ní àwọn agbófinró àtàwọn adoola ẹ̀mí tí ṣiṣẹ níbi iṣẹlẹ ọ̀hún.
"A wá ń rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Borno láti lọ fọkàn balẹ̀, kí wọ́n ma sì lọ tá fele fele lawọn agbegbe ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé."
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló tíì burú julọ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn - Osojumikoro
Bagoni Alkali, ti Ìṣẹ̀lẹ̀ náà soju rẹ ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù àdó olóró yìí ló tíì burú julọ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
Nígbà tó ń bá ileeṣẹ AP sọ̀rọ̀, Alikali ṣalaye pé òun wà lára àwọn èèyàn tó ko àwọn ènìyàn tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà wá sílè ìwòsàn.
"Lọ́wọ́ lọ́wọ́ bayi, ó lè ní ìgbà èèyàn tó farapa nínú ìbúgbàmù náà to n gba itọju nile iwosan"
"Lootọ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn pàdánù ẹ̀mí wọn ní kété táwọn àdó ikú náà bù, èyí tó bá ní lọ́kàn jẹ pupọ"
Bákan náà, Mohammed Hassan, tíí ṣe ọkàn lára ọmọ ẹgbẹ́ adoola ẹ̀mí to máa ń rán àwọn agbófinró lọ́wọ́ sọ pé àwọn tí gbé òkú èèyàn mẹwa kúrò nínú ọjà náà.
"Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó farapa là kò ní pajawiri lọ sílé ìwòsàn, àmọ́ àwọn èèyàn míì tí kú síbẹ̀, tí a sì nílò ẹ̀jẹ̀ pupọ fún itọju àwọn èèyàn tó farapa.
"Ìkọlù yìí si jẹ ọkan lara awọn ìkọlù agbébọn to tíì burú julọ nilu Maiduguri láti ọ̀pọ̀ ọdún seyin"
Lọwọ lọ́wọ́ báyìí, àlàáfíà tí ń padà sílú Maiduguri lẹ́yìn ìbúgbàmù náà.


























