Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ bàbá ẹni ọdún 74 pẹ̀lú oogun olóró l'Abuja

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Ajọ to n gbogun ti oogun oloro lorilẹede Naijiria, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti mu baba agba ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin (74), Ikwuakalom Nwakoro Emeka, fun ẹsun gbigbe oogun oloro cocaine.
Papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe International Airport to wa niluu Abuja ni ọwọ ti ba baba naa pẹlu Cocaine ti wọn lo jẹ iwọn mọkanla (11 kilograms).
Atẹjade ti agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi, fi sita lọjọ Aiku, ṣalaye pe inu awọn ohun jijẹ ni baba naa di awọn cocaine naa si.
O fi kun un pe Ikwuakalom fẹẹ gbe e kọja si orilẹede United Kingdom ni.
Babafemi sọ pe: " Nigba ti a n yẹ ẹru rẹ wo, ìdì cocaine ti iwọn rẹ jẹ mọkanla ni a ri ti wọn fi pamọ sinu awọn ohun jijẹ, titi kan ata gbigbẹ ti wọn ti lọ , ti wọn pọn sinu beba ati fere .
Lasiko ti baba agba yii fẹ wọ baaluu lọ si Heathrow, London, lọjọ Satide, ọjọ kẹrinla oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ni ọwọ ba a bi NDLEA ṣe kede .
Bakan naa ni Agbẹnusọ NDLEA ṣalaye pe ṣaaju ni ọwọ ti kọkọ ba obinrin kan niluu Eko, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Maryam Olalowo.
Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta ọdun 2026 yii lo ni ọwọ ba a.
O ni iwọn cocaine mọkandinlọgọrun-un ( 89 grams) lo fẹ ta, ati eyi ti wọn n pe ni Loud ti iwọn rẹ jẹ ogun (20 grams Canadian Loud).
Babafemi sọ pe ọmọ mẹta ni Maryam ko dani lasiko tọwọ ba a, ọmọ ọwọ si wa ninu wọn pẹlu.
"O jẹwọ pe ọkọ oun, Ibrahim Olalowo Olatunji, lo ni awọn oogun oloro naa, ọjọ naa la si mu ọkọ si atimọle, ti a yọnda iyawo."
"Ibrahim naa jẹwọ fun wa pe oun loun ni awọn oogun to lodi sofin naa, nigba ti iwadii fi ye wa pe ọwọ ofin ti ba a ri, ti ile ẹjọ ju u si ẹwọn ọdun meji aabọ ni 2015 fun ẹsun kan naa."
Femi Babafemi, Agbẹnusọ NDLEA lo ṣafikun bẹẹ.

























