Ààyè ni màmá Deborah Adebola Fasoyin 'Ọdun ń lọ sópin' wà, kò kú – Mọ̀lẹ́bí

Oríṣun àwòrán, CAC Good Women Choir Ibadan
Ẹgbẹ akọrin obinrin rere ijọ CAC ilu Ibadan, iyẹn CAC Good Women Choir Ibadan, ti kede pe irọ ni iroyin to n lọ ni igboro pe mama Deborah Adebola Fasoyin, to lewaju orin "Ọdun n lọ sopin' ti jade laye.
Ọrọ naa lo jade ninu ifọrọwerọ kan ti agbẹnusọ mama, Oluwasoyin Olukorede lọjọ Aje.
Nigba ti BBC Yoruba kan Olukorede lori aago, o ni irọ ni iroyin naa, ati pe alaafia ni mama wa, ko si si nnkan to ṣe e.
Ọkunrin naa to wa pẹlu mama lasiko to n ba wa sọrọ sọ siwaju si pe awọn ti n ka fidio tabi ohun mama silẹ, awọn yoo si fi lede loju opo Facebook laipẹ
O ni "Iroyin ofege ni o, ko si nnkankan to ṣe mama.
"A ti n ka ọrọ wọn silẹ lọw bayii, a si maa gbe sita laipẹ.
"Oju opo Facebook wọn ni a ti maa gbe ọrọ naa sita nitori oju opo Facebook naa ni gbogbo iroyin yii ti bẹrẹ. A maa gbe ọrọ wọn jade loju opo Facebook ẹgbẹ obinrin rere ijọ CAC."
Nibo ni iroyin iku mama Fasoyin ti wa?
Kii ṣe igba akọkọ ree ti iroyin nipa iku mama yoo gbode ni Naijiria nigba ti ko si nnkan to ṣe mama.
Lọtẹ yii, alẹ ọjọ Aiku, ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2026 yii ni iroyin mii tun gbode pe mama ti jade laye lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun un.
Koda, iroyin naa tilẹ sọ pe ọpọ awọn ololufẹ mama atawọn akọrin ẹmi bii tirẹ lo ti bẹrẹ si n ṣedaro rẹ bayii.
Taa ni mama Deborah Fasoyin?
Ọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 1940 ni wọn bi ajihinrere naa niluu Oyo.
O ti pẹ ti mama ti n kọ orin amọ irawọ rẹ tunbọ milẹ titi siwaju si lẹyin ti ẹgbẹ obinrin rere ijọ CAC gbe orin "Odun Nlo Sopin" jade ni nnkan bii ogoji ọdun sẹyin.
Lati igba ti orin naa ti jade titi di asiko yii lawọn eeyan ṣi maa fi orin "Odun Nlo Sopin" ṣe adura ti ọdun ba ti n pari lọ.
Adura wa ni pe ki Eledua lọra ẹmi mama Deborah Fasoyin.




























