Elena, Gbajúmọ̀ ayélujára kú lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ abẹ láti fọn ìdí rẹ̀, ìjọba Eko bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Oríṣun àwòrán, Others
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣokùnfà ikú arábìnrin Elena Jessica Nkwopara èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Elena, ẹni tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ látàrí àwọn ìrora tó ní lẹ́yìn tó lẹ ṣe ìdí ní ilé ìwsòsàn kan ní ìpínlẹ̀ Eko.
Àjọ tó ń rí sí ṣíṣe àmójútó àwọn ilé ìwòsàn ní ìpínlẹ̀ Eko, Health Facilities Monitoring and Accreditation Agency, HEFAMAA nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹta, ọdún 2026 sọ pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà.
Ọ̀gá àgbà àjọ náà, Abiola Idowu nínú àtẹ̀jáde tó wà lójú òpó àjọ náà lórí ìkànnì Facebook sọ pé ilé ìwòsàn tí Elena ti ṣe iṣẹ́ abẹ láti fi kún ìdí rẹ̀ náà ní àkọ́ọ́lẹ̀ pẹ̀lu àwọn, tí wọ́n sì ní àwọn kò ní bo ilé ìwòsàn kankan tó bá ti di ọ̀rọ̀ ààbò àwọn èèyàn.
Wọ́n ní bí ìwádìí ṣe ti ń lọ lọ́wọ́, ìjọba ìpínlẹ̀ Eko yóò ṣe àrídájú rẹ̀ pé gbogbo bí ìwádìí bá ṣe ń lọ ni wọ́n yóò fi máaa tó aráàlú létí, táwọn yóò sì wádìí ìjìnlẹ̀ lórí ohun tó fa ikú arábìnrin náà.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí àjọ náà ṣe sọ, wọ́n ní ohun tó ṣokùnfà ìdí táwọn fi ń ṣe ìwádìí náà ni ìròyìn tó gba orí ayélujára pé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí Elena ṣe iṣẹ́ abẹ náà ni ara rẹ̀ kò yá, kó tó di pé ó jáde láyé.
Wọ́n ní gẹ́gẹ́ bí àjọ tó wà fún ṣíṣe àmójútó àwọn ilé ìwòsàn ní ìpínlẹ̀ Eko, àwọn gbọdọ̀ ṣe àrídájú rẹ̀ pé gbogbo àwọn ilé ìwòsàn tẹ̀lé òfin àti ìlànà tó de iṣẹ́ wọn lórí dídá ààbò bo aráàlú.
Wọ́n ní òfin àti ìlànà wà fún ṣíṣe iṣẹ́ abẹ tó nííṣe pẹ̀lú ṣíṣe àtúnṣe sí àgọ́ ara tó fi mọ́ gbogbo àwọn irinṣẹ́ tí ilé ìwòsàn bẹ́ẹ̀ ń lò.
"A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tó lóòrìn lórí bóyá ìlànà tó tọ́ jẹ́ títẹ̀lé lórí iṣẹ́ abẹ náà, ìwádìí dókítà tó ṣe é àti àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n ṣe ṣáájú, lásìkò àti lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà."
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Elena Jessica?

Oríṣun àwòrán, Unclenasco/Instagram
Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìròyìn gba orí ayélujára pé arábìnrin náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ kejì láti mú àtúnṣe bá ìdí rẹ̀ èyí tí wọ́n ń pè ní BBL.
Fídíò kan tó gba orí ayélujára tí BBC kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣàfihàn obìnrin kan, táwọn èèyàn sọ pé Elena ni wà lórí ìbùsùn ilé ìwòsàn tó sì ń pariwó, táwọn dókítà tó ń ṣiṣẹ́ abẹ sì ń ṣiṣẹ́ lára rẹ̀.
Obìnrin kan tó pe ara rẹ̀ ní àbúrò Elena lórí ìkànnì TikTok, Nelly fìdí ikú Elena múlẹ̀ tó sì fẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn Cynosure Aesthetic Plastic Surgery Hospital tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko pé àwọn ni wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ tó gbẹ̀mí obìnrin náà.
Àmọ́ ilé ìwòsàn náà ní Elena kò kú sọ́dọ̀ àwọn.
Nelly ṣàlàyé pé ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹta, ọdún 2026 ni Elena lọ ṣe iṣẹ́ abẹ láti lọ fa àwọn ọ̀rá láti ara sí ìdí rẹ̀ ní ilé ìwòsàn náà, tó sì sọ àwọn ìrora tó kojú lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà.
Ó ní lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí Elena ṣe iṣẹ́ abẹ náà ló bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ìrora níbi tó ti ṣe iṣẹ́ abẹ náà tí ibẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wú.
Ó fi kun pé àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe lẹ́yìn ìgbà náà fi hàn pé "white blood cell" Elena lọ sókè gidi, tó sì tún ní àwọn kòkòrò kan níbi tó ti ṣe iṣẹ́ abẹ náà àti pé ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ ti ló sílẹ̀ púpọ̀ èyí tó mu kó nílò gbígba ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀.
Ó ní pẹ̀lú gbogbo oògùn tó ń pa kòkòrò tí wọ́n fún -un nílé ìwòsàn níṣe ni àìlera tún lékún. Ó ṣàlàyé pé ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹta ni wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ míì fun láti mú àdínkù bá àwọn ọ̀rá tí wọ́n kó sídìí rẹ̀ bí wọ́n ṣe lérò pé àwọn ọ̀rá náà ti pọ̀ jù ni ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ kò ṣe ṣàn dáadáa.
Nelli fi kun pé iṣẹ́ abẹ kejì tí wọ́n ṣe fun kò mú àdínkù bá ìrora tó ń kojú rárá, tí wọ́n sì darí àwọn láti lọ sí ilé ìwòsàn olùkọ́ni ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn Lagos State University Teaching Hospital, Luth lọ́jọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kejì.
"Nígbà tí a dé Luth, kò sí bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n le gbé Elena sí ní ICU, wákàtí márùn-ún ló ló nínú ọkọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì tó sì ń jẹ ìrora ní gbogbo ìgbà náà.
Ó tẹ̀síwájú pé nọ́ọ̀sì tó tẹ̀lé àwọn láti ilé ìwòsàn Cynosure kò mú abẹ́rẹ́ tàbí oògùn kankan dání láti fi mú àdínkù bá ìrora tí Nelli ń kojú, tí wọ́n sì fi àwọn sílẹ̀ láti máa dá a rán èyí tó mu kí àwọn gbé Elena lọ sílé ìwòsàn míì.
Ó ní ogúnjọ́, oṣù Kejì ni àwọn tún gbe lọ sí ilé ìwòsàn míì nígbà tí àwọn kàn sí dókítà míì níbi tí dókítà náà ti sọ fún àwọn pé bákan méjì ló ṣeéṣe kí ọ̀rọ̀ náà já sí fún Elena.
Ó sọ pé mílíọ̀nù mẹ́fà ni ilé ìwòsàn náà kọ́kọ́ gbà lọ́wọ́ àwọn fún ìtọ́jú Elena fún ọ̀sẹ̀ kan, tí wọ́n sì tún ṣe iṣẹ́ abẹ míì fún-un lọ́jọ́ Kejìlélógún, oṣù Kejì níbi tí wọ́n ti yọ gbogbo ọ̀rá tí wọ́n fi ṣe ìdí fún-un.
Nelli ní pẹ̀lú gbogbo àwọn iṣẹ́ abẹ náà síbẹ̀ níṣe ni ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ ń gbẹ tó sì di ẹ̀bi ikú Elena ru ilé ìwòsàn Cynosure pé wọ́n lo àwọn irinṣẹ́ tí kò mọ́ láti fi ṣe iṣẹ́ abẹ rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Ilé ìwòsàn Cynosure sọ̀rọ̀
Ilé ìwòsàn Cynosure Aesthetic Plastic Surgery Clinics ti wá ṣèkìlọ̀ fún gbogbo àwọn tó bá sọ̀rọ̀ òdì, gbé ìròyìn òfégè tàbí ṣe fídíò èké nípa ilé ìwòsàn náà, tí wọ́n sì ní àwọn fún wọn ní ọjọ́ kan láti yọ wọ́n kúrò tàbí kí wọ́n kojú ìgbésẹ̀ òfin.
Àtẹ̀jáde tí ilé ìwòsàn náà látọwọ́ àwọn agbẹjẹ́rò wọn, Gee Law Firm fi léde lọ́jọ́bọ̀ sọ pé àwọn àwòrán àti fídíò tó ń lọ lórí ayélujára kò wá láti ọ̀dọ̀ àwọn.
Wọ́n ní ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kejì ni àwọn ní kí Jessica Elen máa lọ sílé ìwòsàn kan tó wà ní Mushin kí o le rí ìtọ́jú tó péye níbẹ̀ ṣùgbọ́n táwọn èèyàn rẹ̀ gbe kúrò níbẹ̀ lọ sílé ìwòsàn míì níbi tó kú sí.
Wọ́n ní àwọn kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú àwọn àwòrán àti fídíò tó ń lọ kiri lórí ayélujára nípa arábìnrin náà nítorí ọ̀dọ̀ àwọn kọ́ ni wọ́n ti yà wọ́n.
Ilé ìwòsàn náà ṣàlàyé pé ọ̀dọ̀ àwọn kọ́ ni Elena ti kọ́kọ́ ṣe ìdí, tó sì jẹ́ pé ó kàn wá sọ́dọ̀ àwọn ni fún àtúnṣe ohun táwọn ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ ti kọ́kọ́ ṣe.
Nínú àtẹ̀jáde náà ni ilé ìwòsàn náà ti sọ pé àwọn ṣe gbogbo ohun tó yẹ láti ri dájú pé ó gba ìtọ́jú tó péye, tí àwọn sì ṣe àmójútó ìlera lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ abẹ náà.
Wọ́n ní àwọn ṣe àrídájú rẹ̀ pé lẹ́yìn tó pé ọ̀sẹ̀ méjì ni àwọn ní kí Elena lọ sílé ìwòsàn ńlá fún ìlera tó péye nígbà tí ara rẹ̀ kò balẹ̀.
Wọ́n fi kun pé ìgbésẹ̀ tó yẹ ni àwọn gbé láti fi ránṣẹ́ sílé ìwòsàn míì nígbà tí ara rẹ̀ kò le.
Kí ni BBL?
BBL jẹ́ iṣẹ́ tí wọ́n máa ń ṣe láti mú kí ìdí tóbi, fẹ̀ tàbí yí ródó síi.
Àwọn dókítà tó máa ń ṣe iṣk abẹ yìí máa ń fa ọ̀rá kúrò ni ẹ̀yà ara kan láti fi sí ìdí tàbí kí wọ́n fi ike tí wọ́n ń pè ní silicon si.
Iṣẹ́ abẹ ni ewu ńlá nínú àmọ́ síbẹ̀ iye àwọn èèyàn tó ń ṣe é ń lékún ní ọdọọdún pẹ̀lú ìdá ogun gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe sọ.
Ní ọdún 2023, bíi mílíọ̀nù kan àbọ̀ náírà lọ sókè ni wọ́n fi ń ṣe BBL ṣùgbọ́n tí owó náà ti lékún báyìí gidigidi èyí tó níiṣe pẹ̀lú ilé ìwòsàn, dókítà tó ń ṣe é àti ibi tí iṣk abẹ náà ti ń wáyé.
Àwọn onímọ̀ máa ń fún ẹni tó bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ lámọ̀ràn láti ṣe ìwádìí nípa ilé ìwòsàn àti dókítà tó máa ṣe iṣẹ́ abẹ náà kí wọ́n tó ṣe é nítorí àwọn ìrora tó le tí ẹ̀yìn rẹ̀ jáde.



























