LPDC da ẹ̀sùn ṣíṣe ayédèrú ìwẹ́ ẹ̀rí NYSC tí wọ́n fi kan igbákejì olórí ilé aṣojúṣòfin nù

Benjamin Kalu ní ilé aṣojúṣòfin, ó wọ fìlà, ó ń wo ẹ̀gbẹ́ kan

Oríṣun àwòrán, Benjamin Kalu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ìgbìmọ̀ tó ń rí ìbáwí àwọn onímọ̀ nípa òfin ìyẹn Legal Practitioners Disciplinary Committee, LPDC ti da ẹ̀sùn táwọn kan pè tako igbákejì olórí ilé aṣojúṣòfin, Benjamin Kalu lórí ẹ̀sùn tó níṣe pẹ̀lú kíkópa níbi ètò àgùnbánirọ̀ nù.

Ìgbìmọ̀ náà ní jọ́ táwọn èèyàn náà pè kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti pé ó kọjá ohun tí LPDC le dá sí lọ.

Wọ́n ní ẹ̀sùn tó níṣe pẹ̀lú kíkópa níbi ètò sínsin ìl''u baba ẹni gẹ́gẹ́ bí àgùnbánirọ̀, lílọ sílẹé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ìyẹn Law School àti lílọ sílé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà jẹ́ ohun tó kọjá ohun tí LPDC le dásí lọ.

Wọ́n ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fojú fò ó pé alága àjọ Legal Practitioners' Privileges Committee ni wọ́n kọ ẹ̀sùn náà sí dípò alága LPDC gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lábẹ́ òfin kẹrin ìwé òfin LPDC tọdún 2020, wọ́n ní kò sí ohun tí àwon le ṣe lórí pé ẹ̀sùn náà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

LPDC tẹmpẹlẹmọ pé ohun tí wọ́n dá ìgbìmọ̀ náà kalẹ̀ fún jẹ́ láti ṣe àmójútó àwọn amòfin tó wà lábẹ́ àjọ náà láti ri dájú pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lábẹ́ òfin kẹwàá ìwé òfin ìgbìmọ̀ náà.

Kí ló ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ẹ ó rántí pé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Martins ló gbé ẹ̀sùn kan dìde tako aṣòfin Benjamin Kalu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Benjamin Okezie Osisiogu kí ó tó pàrọ̀ orúkọ, pé ó ṣe àgùnbánrọ̀ lásìkò tó ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ìyẹn Nigerian Law School.

Martins fẹ̀sùn kàn pé ohun tí Kalu ṣe náà lòdì sí òfin tó de ètò sínsin ìlú baba ẹni lẹ́yìn tí èèyàn bá parí nílé ẹ̀kọ́ gíga.

Bákan náà ni àkójọpọ̀ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni kan náà fẹ̀sùn kàn pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé lásìkò tí Kalu wà nílé ẹ̀kọ́ Law School náà ló tún ń ṣe àgùnbánirọ̀ nítorí àwọn ìwé ẹ̀rí tí Kalu ń l]o ṣàfihàn rẹ̀ pé láàárín ọdún 2010 sí 2011 ló parí Law School.

Ẹgbẹ́ náà lásìkò tí Kalu ń búra láti kópa níbi ètò náà ló ní òun kò ní sin ilẹ̀ baba òun ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ìwé ẹ̀rí àgùnbánirọ̀ tó ń lò ṣàfihàn pé oṣù Kẹat ọdún 2011 kan náà ló parí ètò sínsin ilẹ̀ baba rẹ̀.

Wọ́n wá pè fún kí Benjamin Kalu yẹ̀bá kúrò lórí ipò rẹ̀ fún ìgbà kan ná kí wọ́n fi ṣe ìwádìí lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn -án náà.

Àmọ́ Bejamin Kalu ti wá fèsì pé òun kò fìgbà kankan ṣe ayédèrú àwọn ìwé ẹ̀rí tí òun ń lò àti pé àwọn tí wọ́n fẹ́ ba òun lórúkọ jẹ́ àti ipò òṣèlú ni wọ́n gbé ìgbésẹ̀ náà.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Kalu, Lebvinus Nwabughigu sọ pé ẹ̀sùn náà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nítorí kò sí àwọn aláṣẹ kankan tó fìdí ẹ̀sùn àwọn èèyàn náà múlẹ̀.

Agbẹnusọ Kalu sọ pé amòfin tó pójú owó tó sì ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe yẹ.

Àwọn èèkàn ìlú ti wọ́n ti kojú ẹ̀sùn ṣíṣe ayédèrú ìwé ẹ̀rí

  • Uche Nnaji

Ni ọjọ Keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ni minisita fun imọ Sayẹnsi ati imọ ijinlẹ, Uche Nnaji ti kọwe fipo silẹ lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o lo ayederu iwe ẹri lati fasiti orilẹede Naijiria Nsukka, UNN.

Nnaji ni b'oun ṣe kọwe fipo rẹ ki i ṣe pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun pe ayederu ni iwe ẹri fasiti ati iwẹ ẹri fun agunbanirọ oun.

O si n tenu mọ pe oun kawe gboye lati fasiti UNN lọdun 1975, ti iroyin kan si ni ile ẹkọ naa ko le fidi iwe ẹri naa mulẹ.

Fasiti Naijiria, UNN, Nsukka ti sọ wi pe orukọ Minisita imọ ẹrọ ati Sayẹnsi, Uche Geoffrey Nnaji ko si ninu iwe orukọ awọn to kẹkọgboye ni fasiti naa.

Gẹgẹbi awọn alaṣẹfasiti naa ṣe sọ, Fasiti Naijiria, Nsukka ko fun Ọgbẹni Nnaji ni iwe ẹri to n lo lọwọ.

Giwa agba fasiti naa, Ọjọgbọn Simon Ortuanya gbe atẹjade kan sita ninu eyi to ti sọ pe fasiti naa ni ẹri to daju pe pe Ọgbẹni Uchenna Geoffrey Nnaji wọle si fasiti naa lọdun 1981, amọṣa orukọ rẹ ko si lara awọn to kẹkọgboye tabi gba iwe ẹri ni ile ẹkọ giga naa.

  • Aarẹ Muhammadu Buhari

Aarẹ ana lorilẹede NAijiria, Muhammadu Buhari naa ti wẹ ninu agbami ẹsun ayederu iwe ẹri nigba kan ri nigba ti ẹgbẹ oṣelu PDP beere idi ti ko fi si iwe ẹri idanwo aṣegba girama nini iwe ẹri rẹ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe o papa bori ibo ọdun 2015 nigba naa, amọ lẹyin awijare rẹ, ajọ WAEC fun un ni iwe ẹri miran lati rọpo eyi to sọ pe o sọnu lati fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni Buhari gba iwe ẹri naa lọdun 1961.

Aarẹ Bọla Tinubu

Aarẹ Tinubu naa foju wina ẹsun ayederu iwe ẹri lasiko ti awọn kan fi gbe iroyin jade pe ko lọ si ile ẹkọ giga fasiti Chicago state University to n mu iwe ẹri rẹ kiri pe oun lọ. koda oludije ẹgbẹ oṣelu alatako nigba naa, Atiku Abubakar tilẹ lọ si ile ẹjọ lati fi idi eyi mulẹ ki o to di pe ile ẹjọ ati awọn alaṣẹ Fasiti naa sọ pe lootọ ni Tinubu lọ si ile ẹkọ giga Fasiti naa.

  • Dino Melaye

Sẹnetọ Melaye pẹlu ti la iriri ẹsun iwe ẹri ayederu kọja ri lọdun 2017 nigba ti iwe iroyin abẹle kan ni Naijiria, Sahara Reporters fi ẹsun kan an pe ko kẹkọgboye ni fasiti Ahmadu Bello to sọ pe oun lọ

Amọṣa Fasiti naa jade sita lati sọ pe akẹkọjade awọn ni Dino Melaye bi o tilẹ jẹ pe wọn ni awọn aidọgba kan jẹyọ ninu iwe esi idanwo ile ẹkọ giga naa.

Bi o tilẹ jẹ pe Fasiti Havard ati London School of Economics ni kii ṣe akẹkọgboye fasiti awọn nigba naa.

  • Goodluck Jonathan

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan pẹlu ti la agbami ẹsun ayederu iwe ẹri kọja nigba ti aarẹ tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ kede ni gbangba pe Jonathan ko pari ẹkọ oye ọmọwe to n fi kun iwe ẹri ẹkọ rẹ, amṣa fasiti ilu PortHarcourt ti sọ ọ lemọlemọ pe akẹkọgboye imọ ijinlẹ akọkọ, ikeji ati ti ọmọwe ni fasiti awọn ni Jonathan

  • Kemi Adeosun, minisita fun eto iṣuna 2015 - 2018

Lara awọn to ti ni iriri yii ni minisita fun eto iṣuna nigba kan ri, Kemi Adeosun lọdun 2018 nigba ti iroyin jade pe o lo ayederu iwe ẹri agunbanirọ lati gba iṣẹ gẹgẹbi minisita labẹ ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

Lẹyin ọpọ awuyewuye lo kọwe fi ipo silẹ nigba naa.

  • Stella Oduah

Sẹnetọ ni Stella Oduah ni ile igbimọ aṣofin agba Naijiria ki o to di pe ọrọ iwe ẹri rẹ di ariwo.

Stella Oduah sọ pe oun gba iwe ẹri imọ iṣiro ow oni fasiti St. Paul's College to w ani Virginia lorilẹede Amẹrika laarin ọdun 1978 si 1982 ki aṣiri to tu pe ko lọ rara.