Aáwọ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàárín APC àti Accord ní ìpínlẹ̀ Osun lórí ṣọ́ọ̀bù kíkọ́

Àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Accord Party

Oríṣun àwòrán, APC/ACCORD PARTY/FACEBOOK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

‎‎Niṣe ni ọrọ di ẹni ori yọ o dile ni owurọ ọjọ Kejila, osu Kẹta ọdun 2026 nigba ti aawọ nla bẹ silẹ laaarin ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu Accord Party tẹka ipinlẹ Osun.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe awọn janduku ọmọ ẹgbẹ oṣelu Accord lo yari pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ko lẹtọọ lati kọ ṣọọbu igbalode si ọja Timi to wa ni agbegbe Oke Gaada niluu Ẹdẹ, ipinlẹ Osun.

‎‎Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ede, arakunrin Adeyemi Elliot to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo fẹ ṣe ifilọlẹ ṣọọbu igbalode si ọja Timi to wa ni agbegbe ki awọn janduku to ṣadede da eto naa ru.

‎‎Ọkan lara awọn ti ọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe, ṣadede ni awọn janduku ti wọn de fila ọmọ ẹgbẹ oṣelu Accord yawọ ibi ti wọn ti fẹ ṣe ifilọlẹ ṣọọbu igbalode naa ti wọn si bẹrẹ si ni ju okuta lu gbogbo awọn to pejọ sibẹ.

‎‎O ni eleyii lo mu ki gbogbo awọn eeyan to peju sibẹ tuka, ti ọrọ naa si di bo o lọ ko o ya fun mi.

‎O sọ pe igbesẹ naa mu ki awọn ẹṣọ aabo ara ẹni ni aabo ilu ati awọn ọlọpaa bẹrẹ si ni yin afẹfẹ tajutaju si oke lati le daabobo awọn eeyan to wa nibẹ.

‎‎Nigba ti BBC News Yoruba kan si alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ede, ‎Arakunrin Adeyemi Elliot, o salaye pe ṣọọbu igbalode ni awọn fẹ ṣe ifilọlẹ ti eto si ti fẹ bẹrẹ ki awọn to ṣadede ri awọn janduku ti wọn yawọ ibi ti wọn ti fẹ ṣe ifilọlẹ sọọbu igbalode naa, ti wọn si bẹrẹ si ni ju okuta lu awọn.

‎O ni awọn janduku naa de fila ọmọ ẹgbẹ oṣelu Accord si ori wọn, ti wọn si n sọ fawọn pe awọn ko ni aṣẹ kankan lati kọ sọọbu igbalode si ọja Timi rara.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎‎Arakunrin Adeyemi tun salaye wi pe idi ti awọn fi fẹ kọ sọọbu igbalode naa ni lati maa pawo wọle si apo ijọba ibilẹ ati ti ipinlẹti wọn yoo si tun mu ki ọrọ aje agbegbe naa ati ipinlẹ Osun gbe pẹẹli sii.

‎O ni ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn ero to wa ni agbegbe naa lo fara pa nibi ikọlu naa ti ọpọ ninu wọn si wa ni ile iwosan lọwọlọwọ bayii.

‎Ninu ọrọ tirẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Abiodun Ojelabi, salaye pe, ọrọ naa ti de eti awọn, bẹẹ si ni iwadii ti bẹrẹ lori ikọlu naa to si ṣeleri pe ẹnikẹni ti ade ọrọ naa ba ṣi mọ lori yoo fi imu ko ata ofin.

‎‎O wa fi da gbogbo olugbe ipinlẹ Osun loju pe ki wọn lọ fi ọkan balẹ lori ija oṣelu, pe awọn ti ṣetan lati pese aabo to daju fun ẹmi ati dukia awọn araalu.

‎Titi di owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹtala, oṣu Kẹta, gbogbo akitiyan akọroyin BBC News Yoruba lati ri ẹgbẹ oṣelu Accord ati ijọba ipinlẹ Osun ba sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo jasi pabo.

Gbogbo awọn ti a pe ni ko gbe ẹrọ ibanisọrọ wọn, ti wọn ko si dahun sawọn atẹjiṣẹ ti a fi ranṣẹ si wọn.