Ìdí rèé tí Bàbá Mohbad ṣe tako ibùdó àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ tí wọn ti fẹ́ ṣe DNA fún Liam ọmọ Mohbad nílùú òyìnbó

Oloogbe Mohbad ati iyawo rẹ Wunmi gbe Liam lọwọ

Oríṣun àwòrán, @_C33WHY_/INSTAGRAM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọgbẹni Joseph Aloba tii ṣe baba gbajugbaja akọrin takasufe to dolóògbé, Ilerioluwa Aloba t'awọn eeyan mọ sí Mohbad, ti kọminu lori awọn laabu ti wọn ti fẹ ṣe ayẹwo DNA fún Liam ọmọ Mohbad.

Ọrọ yii jade ninu atẹjade ti amofin Oladayo Ogungbe to n sojú Ọgbẹni Aloba Baba Mohbad buwọ́lù.

Agbẹjọro Ogungbe ni ile ẹjọ paṣẹ lọjọ kẹrinlelogun oṣu Keji ọdun yii pe ki ayẹwo DNA naa waye ni laabu mẹta ti ijọba ipinlẹ Eko ati gbogbo awọn tọrọ kan fọwọ si lati le fi ìdí òdodo múlẹ̀.

Awọn laabu ọhun ni DNA Diagnostics Centre ni Fairfield, Ohio, l'Amerika, Alpha Biolabs, Warrington, ni UK ati Advanced Histopathology Laboratory ltd ni London.

Amofin naa ṣalaye pe olupẹjọ lo bèèrè fún ìwádìí àwọn laabu naa ki wọn to ṣe ayẹwo DNA níbẹ.

Ogungbe ni lẹyin iwadii ọhun ni olupẹjọ sọ pe oun n kọminu lori meji lara awọn laabu mẹtẹẹta ti wọn ti fẹ lo fun ayẹwo ọhun.

Agbẹjọro naa ṣalaye pe iwadii lori Alpha Biolabs ati Advanced Histopathology Laboratory fi han pe wọn kii ṣe ayẹwo DNA pẹlu ara oku eeyan ti wọn ti fi Kẹmika tọju.

Amofin naa ni awọn ti fi ọrọ naa to ile ẹjọ́ leti.

Ọgbẹni Ogungbe tun ṣalaye pe irọ to jinna si ootọ lọrọ tawon eeyan kan n sọ pe baba Mohbad mọ ọn mọ mu awọn laabu mẹtẹẹta naa ni.

O ni ọkan ṣoṣo lara laabu mẹta ọhun ni baba Mohbad buwọ́lù.

Amofin Ogungbe ni baba oloogbe naa n fẹ ki ayẹwo DNA ọhun waye nibi to dara fún iru ayẹwo bẹẹ.

Ṣaaju ni ile-ẹjọ majisreeti to wa ni Ikorodu nipinlẹ Eko pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ṣe ayẹwo DNA fún Liam ọmọ Mohbad to doloogbe.

Majisreeti Adefisoye Sonuga pàṣẹ naa nigba to n dajọ lori ẹbẹ Ọgbẹni Aloba lati mọ bo ya lóòótọ́ ni Liam jẹ ọmọ Mohbad.

Loṣu Kẹsan an ọdun 2023 ni Mohbad jade laye lojiji, eyi to ti fa awuyewuye lori ogun rẹ.

Oṣu kẹrin ọdun 2023 yìí kan naa ni wọn bi Liam ọmọ rẹ.

Ta ni Mohbad, ki ló ti wáyé saájú lórí ikú rẹ̀?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ Kẹta, oṣu Kiini, ọdun 1996 ni gbajugbaja akọrin takasufee, Ilerioluwa Oladimeji Aloba, tọpọ eeyan mọ si Mohbad de ile aye, ko ba pe ọdun ẹni ọgbọn ọdun lọdun 2026 yii to ba jẹ pe o ṣi wa laye.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Mohbad nigba to ku lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023.

Iku rẹ mu awuyewuye dani lori ayelujara, ti ọpọ si n tọka si ẹni to ni ileeṣẹ orin to n gbe e sita tẹlẹ, Naira Marley, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa tabi ile-ẹjọ ko tii fidi eyi mulẹ pe lootọ ni.

Oṣu Keji, ọdun 2022, ni Mohbad kuro nileeṣẹ to n gbe orin sita, Marlian Music to jẹ ti Naira Marley.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 gbe igbimọ oluwadii ẹlẹni mẹtala dide lati ṣe iwadii iku onkọrin ọhun.

Iku rẹ lo tun fa bi awọn ọlọpaa ṣe fi kele ofin gbe Naira Marley ati gbajumọ kan nipinlẹ Eko, Balogun Eletu, ti wọn tun n pe ni Sam Larry, ati awọn miran.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 ni wọn lọ wu oku Mohbad fun ayẹwo lati mọ iru iku to pa a.

Latigba ti esi ayẹwo lati mọ iru iku to pa Mohbad lasiko ti ogo rẹ n buyọ, ti jade, ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n lọ kaakiri ori ikanni ayelujara.

Oriṣiriṣi awuyewuye to n lọ nigboro yii lo mu ki BBC YORUBA kan si baba oloogbe naa, Ọgbẹni Joseph Alọba lati mọ boya esi ayẹwo ọhun tẹẹ lọrun tabi ko tẹẹ lọrun.

Ṣugbọn nigba to n ṣalaye, Ọgbẹni Joseph Alọba jẹ ko di mimọ pe oun ko nigbagbọ kankan ninu esi ayẹwo naa ti wọn gbe jade.

Màá ṣe àyẹ̀wò DNA fọ́mọ Mohbad, kí wọn tó sin-ín, ẹ má gba òkú ọmọ mi lẹ́yìn mi - Bàbá Mohbad

Joseph Aloba, tíí ṣe bàbá Mohbad si lo kede saaju pe ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gbìyànjú láti sin òkú ọmọ òun lẹ́yìn òun.

Nínú fídíò kan tó fi sórí ayélujára Facebook, ni bàbá Mohbad ti ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn kan ṣe ń pè fún pé kí wọ́n gbé òkú ọmọ náà kalẹ̀ fún àwọn, kí àwọn lọ sin òkú ọmọ náà.

Bàbá ọmọ náà ní ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ lọ gba òkú ọmọ òun láì gba àṣẹ lọ́wọ́ òun.

Ṣáájú ni àwọn kan ti ń ní kí àwọn ọlọ́pàá gbé òkú ọmọ náà sílẹ̀ fún àwọn, kí wọ́n lè sin ọmọ náà bó ṣe tọ́.