Ẹ̀yin aráàlú, ẹ láṣẹ láti ya fídíò àwọn ọlọ́pàá lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n sì gbọdọ̀ lẹ orúkọ wọn sáyà - Adájọ́

Oríṣun àwòrán, Other
Ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Warri, nipinlẹ Delta, ti gbe idajọ kalẹ pe awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni ẹtọ lati ya fidio awọn oṣiṣẹ ọlọpaa lẹnu iṣẹ wọn nigba kugba.
Onidajọ H. A. Nganjiwa lo gbe idajọ naa kalẹ lori ẹjọ to ni nọmba idanimọ FHC/WR/CS/872025, to si tun tẹnu mọ pe awọn ọlọpaa gbọdọ wọ orukọ wọn si ara aṣọ ileeṣẹ ọlọpaa, lasiko ti wọn ba ṣe iṣẹ lọwọ.
Nganijiwa tun ni oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ko gbọdọ kọlu araalu tabi fi ofin mu nitori o fẹ ya fidio rẹ.
Bakan naa ni ileẹjọ tun da ẹjọ olupẹjọ, Maxwell Uwaifo laare, pe ki ileeṣẹ ọlọpaa san owo gba mabinu milọnu marun un naira ati milọnu meji owo pe wọn tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ.
"Idajọ yii ni ipa nla lori iwuwasi awọn ọlọpaa kaakiri Naijiria ," Uwaifo sọ ninu atẹjade kan to fi ransẹ si ileeṣẹ iroyin abẹle Pemium Times lọjọ Iṣẹgun.
Bawo ni igbẹjọ naa ṣe bẹrẹ?
Arakunrin Uwaifo lo pe ẹjọ tako bii awọn oṣiṣẹ ọlọpaa kan ṣe kuna lati wọ orukọ wọn si ara aṣọ, ti wọn si n da awọn eeyan duro loju opopona.
Ẹjọ naa lo ni orukọ ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Ileeṣẹ ọlọpaa, agbẹjọro agba fun orilẹede Naijiria ati ẹka to n ri si ileeṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bii olujẹjọ.
Ninu iwe ẹjo rẹ, Uwaifo ni oun ati ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ni awọn ọlọpaa ti da duro pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ ti ko ni danimọ pe ọlọpaa ni wọn.
O ni lọdun 2025, oun ṣe alabapade awọn ọlọpaa kan ni ọna Warri si Benin, ti wọn si da oun duro ṣugbọn ọrọ di wahala nigba ti oun fẹ ya fidio wọn.
O tẹsiwaju pe irufẹ eyi tun waye ni oṣu kẹfa ọdun 2025 bakan naa ni ọna Effurun Roundabout.
Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori eyi?
Ninu oṣu kejila ọdun 2023, ileeṣẹ ọlọpaa sọ fun gbogbo araalu pe wọn aṣẹ lati ya fidio awọn oṣiṣẹ ọlọpaa lasiko iṣẹ wọn.
Ninu ọrọ rẹ loju opo ayelujara, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lasiko naa, Olumuyiwa Adejobi ṣalaye pe yiya awọn ọlọpaa lasiko iṣẹ ki n ṣe ẹsẹ rara.
Ọpọ fọnran lo oju opo ayelujara ti ṣafihan bi awọn ọlọpaa ṣe n kọlu araalu nitori wọn ya fidio wọ lasiko iṣẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa bu ẹnu atẹlu iṣẹlẹ naa ti wọn si ṣe ileri pe awọn yoo fiya jẹ awọn ọlọpaa bẹ labẹ ofin.
"Araalu ni ẹtọ labẹ ofin lati ya fidio awọn ọlọpaa lasiko iṣẹ wọn, awọn ọlọpaa gbọdọ mọ pe awọn ṣe iṣẹ ni ilana ti ofin la kalẹ."


























