Adájọ́ pàṣe kí agbẹjọ́rò Sowore kúnlẹ̀ torí àrífín, agbẹjọ́rò ní ó di ayé àtúnwá

Omoyele Sowore ati agbẹjọroo rẹ

Oríṣun àwòrán, OMoyele Sowore

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbas-gbos waye nile ẹjọ lasiko igbejọ ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS pe ajigbara to dije sipo Aarẹ lọdun 2023, Omoyele Sowore.

Họwuhọwu naa ko ṣẹyin bi agbẹjọro Sowore ṣe rọ ile naa pe ko sun igbẹjọ ọhun siwaju fun ọjọ gbọọrọ amọ ti adajọ si ni ko kunlẹ siwaju ile ẹjọ naa latari bo ṣe n gbe ohun soke niwaju oun.

Iroyin ni inu bi adajọ Mohammed Umar, ti ile ẹjọ giga ilu Abuja, latari bo ṣe ni ohun agbẹjọro Sowore le mọ oun, eyii to jẹ arifin si ile ẹjọ ọhun.

Bi ọrọ ṣe bẹrẹ ati ohun to ṣẹlẹ nile ẹjọ

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọrọ naa bẹrẹ lẹyin ti Sowore sọ loju opo ayelujara X ati Facebook rẹ pe ọdaran ni Aarẹ Tinubu.

DSS kọ lẹta si Sowore ati ileesẹ X, to fi mọ Meta lasiko naa pe ki wọn yọ ọrọ naa latari pe o tabuku Aarẹ Tinubu, amọ Sowore atawọn ileeṣẹ ọhun kọ lati ṣe bẹẹ.

Wayi o, asiko ti igbẹjọ ọhun n lọ lọwọ lana ọjọ Iṣẹgun ni Sowore sọ fun ile ẹjọ pe oun ni irinajo to pọ lati rin kaakiri Naijiria lati ko awọn eeyan jọ tako igbiyanju Tinubu lati dije fun saa keji keji lọdun 2027.

O ni nitori naa, ki ile ẹjọ sun igbẹjọ naa siwaju fun ọjọ gbọrọ.

Amọ Adeolu Kehinde, SAN, to n lewaju ikọ olupẹjọ tako o, eyii to mu ki agbẹjọro Sowore, Marshal Abubakar naa dide sọrọ.

Abubakar ni ṣe ni ijọba apapọ n mura lati sọ onibara oun si ẹwọn.

Adajọ Umar, to ti kọkọ kilọ fun Abubakar pe ohun rẹ le, ni ko gbẹnu dakẹ.

Ṣugbọn lẹyin ti agbẹjọro naa kọ lati ṣe bẹẹ, adajọ ni ko jade siwaju ile ẹjọ ko si kunlẹ ẹsẹ mejeji gẹgẹ bii ijiya ohun to ṣe.

Abubakar kọ lati kunlẹ, o si sọ fun adajọ naa pe ikunlẹ kii ṣe ijiya labẹ ofin Naijiria, nitori naa, oun ko ni kunlẹ gẹgẹ bii adajọ naa ṣe paṣẹ.

Ọrọ naa mu ki awọn agbẹjọro mii nile ẹjọ bẹrẹ si n bẹ adajọ Umar ko jebure awo olugbẹbẹ.

Lẹyinorẹyin, adajọ Umar sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 ti a wa yii.

Ki ni awọn eeyan n sọ lori iṣẹlẹ yii?

Ọrọ naa jẹ kayeefi si ọpọ araalu pe adajọ paṣẹ fun agbẹjọro ko kunlẹ siwaju oun, wọn si ti n fi erongba wọn lede lori rẹ.

Lara awọn to n sọ erongba wọn lori iṣẹlẹ naa ni ẹgbẹ 'Take it back movement.'

Ninu atẹjade ti adari ẹgbẹ ọhun, Sanyaolu Juwon, fi lede, o ni o jẹ ohun itiju pe adajọ n sọ fun odidi agbẹjọro lati maa kunlẹ niwaju ile ẹjọ.

Ẹgbẹ ọhun ni iwa agbẹjọro naa da bii igba ti wọn ba fẹ mọọmọ da Naijiria pada si ayẹ atijọ ni, irufẹ iwa bẹẹ ko si ṣe itẹwọgba.

Wọn ni inu ile ẹjọ ko wa fun ati maa yẹyẹ ẹlomii, o jẹ ibi ti araalu ti n gba idajọ ododo.

Lẹyin naa ni ẹgbẹ ọhun kede pe ki iọba Aarẹ Bola Tinubu jawọ ninu ẹjọ to n ba Sowore ṣe nitori igbẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ.