Ilẹ̀ rírì àti omiyalé gbẹ̀mí èèyàn 102 ní Ethiopia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, eeyan mejilelọgọrun lo ti padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ilẹ riri ati omiyale to waye lẹyin ojo arọrọda ni Ethiopia.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ kede pe eeyan ọgbọn lo ku ki iye awọn to ku naa to tun le si laarin wakati mẹrinlelogun.
Lasiko kan, ọlọpaa ni eeyan mẹrinlelọgọta ti jade laye nigba ti wọn si n wa ọpọ awọn mii.
Pupọ awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ni wọn jẹ awọn ti wọn n gbe ni awọn ibi to ga eyii ti iṣẹlẹ naa pa lara lasiko ti ilẹ bẹrẹ si n ya.
Laarin ọjọ diẹ sẹyin ni ojo arọrọda kọlu ila oorun Afrika, eyii to mu ẹmi eeyan mẹrinlelogun lọ niluu Nairobi, orilẹede Kenya.
Awọn to n woye oju ọjọ sọ pe iji lile yoo tẹsiwaju lati maa kọlu agbegbe naa, wọn si ni ayipada oju ọjọ wa lara nnkan to n fa a.
Gomina agbegbe guusu Ethiopia, Tilahun Kebede ti fi ọrọ ibanikẹdun ṣọwọ si mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ sọ pe ojo to kọ ti ko da lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Fun odidi ọjọ meji gbako ni ojo fi rọ niluu Arba Minch ati agbegbe rẹ, eyii to ba ọpọ dukia jẹ.
Wayi o, wọn ti wa kilọ pe o ṣeeṣe ki ojo ati ilẹ riri naa ṣi tẹsiwaju.
Ilẹ to ya ti di oju ọpọ opopona, bẹẹ naa ni agbara omi ti gba ọpọ afara, eyii to mu ki ijọba kede pe ki awọn araalu ma sun gbera.
Awọn onimọ sayẹnsi ti kilọ leralera pe ayipada oju ọjọ to ti ọwọ awọn eeyan wa ti n fa ojo arọrọda lọpọ ibi.
O le ni eeyan 229 to padanu ẹmi wọn lẹyin ti iṣẹlẹ ilẹ riri waye lagbegbe Geze Gofa ninu oṣu Kẹfa ọdun 2024.



























