Agbódegbà fáwọn Ajínigbé méjì la mú, ìrọ́ ni pé ọwọ́ tẹ afurasí agbébọn mẹ́rin ní pápákọ̀ òfurufú Akure - Ọlọ́pàá tako FAAN

Ẹnu ọna abawọle Papakọ ofurufu Akure. Ọkọ agbofinro duro siwaju ibẹ, ti awọn asọna si si ẹnu ọna kan silẹ ninu meji

Oríṣun àwòrán, FAAN

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti kede sita pe irọ to jinna sootọ ni iroyin kan to gba ori ayelujara kan, eyi to ni ọwọ tẹ afurasi agbegbọn mẹrin ni papakọ ofurufu nilu Akure.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayomi Jimoh fisita lọjọ Aje lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ajọ to n ri si irinna ọkọ ofurufu lorilẹ ede Naijiria (FAAN) ti kede pe ọwọ tẹ afurasi agbebọn mẹrin ninu ọgba papakọ ofurufu nilu Akure.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ FAAN, Henry Agbebire fi lede lọjọ Aiku lo salaye pe awọn afurasi naa gbiyanju lati na papa bora, sugbọn awọn esọ alaabo fi panpẹ ọba mu awọn mẹrin, ti wọn si fa wọn le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ.

"Iwadi wa nibẹrẹ pẹpẹ fihan pe awọn afurasi ti ọwọ tẹ lo n finmufinlẹ fawọn agbegbọn eyi to n mu kiwa ijinigbe gbinlẹ lagbegbe Akure

Sugbọn ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti wa sẹ pe irufẹ isẹlẹ yii ko waye rara ni Papakọ ofurufu ilu Akure, ti ko si sẹni to fẹ dena eto aabo to peye nibẹ.

Atẹjade naa salaye pe lootọ ni awọn araalu kan ta awọn lolobo nipa ọsẹ awọn afurasi ajinigbe ni agbegbe Eleyewo nilu Akure.

Ni kete ti iroyin naa si to awọn leti, lawọn ti gbe igbesẹ, ti ileesẹ ọlọpaa naa si lọ sagbegbe naa, eyi to mu ki ọwọ tẹ afurasi meji.

"Iwadi wa nibẹrẹ pẹpẹ fihan pe awọn afurasi naa lo n finmufinlẹ fawọn agbegbọn eyi to n mu kiwa ijinigbe gbinlẹ lagbegbe naa.

Awọn afurasi ọhun si ti n sọrọ nipa isẹlẹ naa, ti iwadi si n lọ lati mu awọn afurasi ajinigbe to ku naa."

"Iroyin ofege n pe ọwọ ba afurasi agbebọn mẹrin ni papakọ ofurufu ni Akure, o le si araalu lọna, to si le da inu fo, aya fo silẹ laarin awọn araalu"

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo wa rọ awọn araalu lati kẹyin sawọn iroyin ti ko kunju iwọn, tori irọ nla ni pe awọn mu afurasi agbegbọn ni papakọ ofurufu ni Akure.

"Iroyin naa jẹ ofege, eyi to le si araalu lọna, to si le da inu fo, aya fo silẹ laarin awọn araalu.

A si n rọ awọn araalu lati maa ba isẹ oojọ wọn lọ lai si ibẹru tabi ifoya kankan."

Ileesẹ ọlọpaa Ondo wa fọwọ sọya fawọn araalu ipese aabo to peye fawọn dukia ijọba bii papakọ ofurufu ko yinjẹ rara

Àwọn agbébọn tí wọ́n gbé ìbọn kọ́rùn àti sọ́wọ́, wọ́n fi aṣọ bojú

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìbẹ̀rù bojo gbalẹ̀ bí ọwọ́ agbófinró ṣe tẹ afurasí agbébọn mẹ́rin ní pápákọ̀ òfurufú Akure

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ṣe ni ọrọ di bo o lọ ko yago fun mi ni papakọ ofurufu ilu Akure ni ipinlẹ Ondo ni ọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2026 bi ọwọ awọn agbofinro ṣe tẹ awọn afurasi agbebọn kan ni agbegbe papakọ ofurufu naa.

Iṣẹlẹ yii lo waye lẹyin tawọn agbẹ kan fi ariwo ta nigba ti wọn ri awọn afurasi agbebọn naa lori ọkada ti wọn n rin pẹlu ifura lẹyin papakọ ofurufu naa pẹlu awọn ohun ija lọwọ ni agbegbe Eleyewo, Akure, ipinlẹ Ondo.

Àwọn ti iṣẹlẹ naa sọju wọn sọ fun awọn akọroyin pe ohun to fa inu fu aya fu ni agbegbe naa ni bi wọn ṣe ri awọn agbẹ naa ti wọn n sare, ti wọn si n pe fun iranlọwọ lẹyin ti wọn ri awọn afurasi naa to n tọ wọn bọ lori ọkada.

Awọn agbẹ naa, gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ro wi pe awọn afurasi naa n bọ lati ṣe ikọlu si wọn ko to di pe awọn ẹṣọ aabo de ibẹ, ti wón si fi poro ofin gbe awọn afurasi ọhun.

Ariwo awọn agbẹ yii lo jẹ kawọn ẹṣọ aabo to fi mọ awọn ologun oju ofurufu, awọn ọmọ ogun ilẹ atawọn ẹṣọ aabo mii lati lọ pawọpọ nawọ gan awọn afurasi ọhun.

Àtẹ̀jáde tí FAAN fi léde lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Oríṣun àwòrán, FAAN/X

A maa mọ odi yika awọn papakọ ofurufu to wa ni Naijiria - FAAN

Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, ajọ to n ri si irinna ọkọ ofurufu lorilẹ ede Naijiria (FAAN) ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa Henry Agbebire fi lede lọjọ Aiku sọ pe awọn afurasi naa gbiyanju lati na papa bora, sugbọn awọn esọ alaabo fi panpẹ ọba mu awọn mẹrin, ti wọn si fa wọn le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ.

Ajọ FAAN gboriyin fun awọn esọ aabo ati ifọwọsowọpọ laaarin ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ologun, awọn fijilante, to fi mọ Amọtẹkun bi wọn ṣe daabo bo awọn arinrinjo ni papakọ ofurufu naa, ti wọn si satenumọ pataki ifowosowopo awọn esọ alaabo lati gbogun ti iwa ọdaran lawujọ.

Agberibe ṣalaye pe FAAN pẹlu idari ijọba apapọ ti bẹrẹ iṣẹ lati mọ odi kaakiri awọn papakọ ofurufu jakejado orilẹ ede Naijiria.

Atẹjade naa fi kun pe ajọ FAAN tẹsiwaju lati maa dabo bo awọn arinrinajo ati awọn ilu to wa ni ayika papakọ ofurufu naa to fi mọ gbogbo papakọ ofurufu orileede yii, kí àwọn eniyan le maa gunle irinajo wọn lai si ibẹru.

Wọn ni awọn ti fa awọn afurasi naa le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadii to peye.

A ti bẹrẹ iwadii lori awọn afurasi agbebọn naa - Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo naa ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa, Abayomi Jimoh fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn akọroyin ni ilu Akure.

Bakan naa lo ni ọwọ tun ti tẹ awọn afurasi meji mii ti wọn fura si pe wọn ni nnkan ṣe pẹlu ijinigbe to n waye lagbegbe Ilu-Abo atawọn agbegbe rẹ.

Jimoh ni ọkan lara awọn afurasi naa lo jẹ ọlọkada to si n ṣe iranwọ fawọn ajinigbe ni agbegbe naa nipa biba wọn ra ounjẹ atawọn ohun elo mii ti wọn nilo ni awọn ibi ti wọn fara pamọ si.

Ilu Eleyowo atawọn ilu mii to wa ni agbegbe rẹ ni ijọba ibilẹ Akure North lo ti n koju awọn ikọlu ijinigbe atawọn ikọlu mii latọwọ awọn agbebọn ni ibẹrẹ ọdun yii.

Eeyan mẹta, to fi mọ awọn oloyun kan ni wọn jigbe ni ilu Eleyowo, Ilu Abo ati Ayede ni ibẹrẹ ọdun yii nikan.

Awọn eeyan naa ni wọn gba itusilẹ lẹyin ti wọn lo ọjọ diẹ ni akata awọn ajinigbe naa lẹyin tawọn ẹbi wọn san owo itusilẹ fawọn ajinigbe naa.

Awọn agbebọn naa tun ṣe ikọlu si Ilu Abo nibi ti wọn ti ji eeyan mẹta gbe lasiko ti wọn n ṣiṣẹ ninu oko wọn ni ẹgbẹ papakọ ofurufu ni ọjọ Aje ọsẹ to kọja.

Lara awọn to lugbadi ikọlu awọn agbebọn naa ni Joseph Aladesuyi to jé akọwe ijọba ibilẹ Okeluju LCDA ni ẹkun iwọ oorun Akoko North-West, ipinlẹ naa.