Ọkọ̀ bọ́ọ̀sì akèrò kó s'ódò nílùú Ibadan, èèyàn mẹ́ta kú

Oríṣun àwòrán, Oyo Affairs
Bọọsi akero kan to n gbe eeyan mẹjọ sọ ijawọ rẹ, to si morile ninu odo kan to wa agbegbe Amuloko ni ijọba ibilẹ Ona Ara niluu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo.
Eeyan mẹta lo padanu ẹmi ninu iṣẹlẹ yii, ti awọn marun un yooku si farapa yanayana.
Ọga agba fun ileeṣẹ panapana nipinlẹ Oyo, Moroof Akinwande ni kete ti awọn gba ipe lati ọdọ arabinrin kan ti o pe orukọ rẹ ni Fadeke Yusuf ni awọn gbera wa sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Ileeṣẹ panapana ni awọn ri ọkọ bọọsi ti ẹya Suzuki pẹlu nọmba idanimọ Osun LEW 484 XA to ko sinu odo.
"A ri ẹmi eeyan marun un doola, ti a si ti gbe wọn lọ si ile iwosan Ona Ara ni Jegede, ti awọn mẹta yooku si padanu ẹmi wọn, ti a si tun gbe oku wọn fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Ogbere.," Akinwande ṣalaye.
Iwadii fihan pe ere aṣapajude lo ṣokunfa ijamba naa, Akinwande ni o ṣe koko ki awọn awakọ ma wa ọkọ wọn pẹlu suuru ati fifi oju si ọna lati dena de ijamba ọkọ,
"Iranlọwọ wa lati ọdọ ajọ to n risi opopna ni ipinlẹ Oyo, OYRTMA ati ọdọ alaga ijọba ibilẹ Ọna Ara, Glorious Temitope, lati tete ri awọn eeyan naa yọ sita.
Oṣojumikoro ni ijamba dẹrubani pupọ, to si ṣalaye bi ọkọ ṣe ya sinu odo naa.
Awọn eeyan agbegbe naa wa kesi awọn agbofinro loju opopona naa lati ṣe iṣe wọn bi iṣe nipa riri daju pe awọn awakọ tẹle ofi Irinna loju opopona bi ti Amuloko.


























